Ìjọba Eko gbẹ́sẹ̀lé NURTW ní Lagos Island, ọlọ́pàá mú àwọn méjì míì lórí ìjà ìgboro Idumota

MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, @gboyegaakosile

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbẹsẹle iṣẹ awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ, NURTW, ni Lagos Island, ni ipinlẹ Eko.

Awọn agbegbe tin ọrọ naa kan ni Eyin Eyo, Church Street ati Idumota,

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ija igboro to waye lọsẹ to kọja.

Agbẹnusọ gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile lo fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ lọjọ Abamẹta.

Bakan naa ni olubadamọran pataki si ijọba Eko lori irinkerindo oju popo, Oluwatoyin Fayinka sọ nibi ipade kan pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ọhun, atawọn mii ti ọrọ naa kan pe awọn oṣiṣẹ ijọba Eko, Lagos State Parks Monitoring Authority, LSPMA, ni yoo maa ṣiṣẹ ni Eyin Eyo lasiko yii.

O ni awọn gbe igbeṣe yii lati dena rogbodiyan ati ija igboro mii to ṣeeṣẹ ko waye lẹyin ti akọkọ.

Fayinka fi kun pe awọn ọtẹlẹmuyẹ RSS ti wa nikalẹ lagbegbe Idumota lati fi imu ẹnikẹni to ba ta felefele danrin.

Ṣaaju ni ẹmi awọn eeyan kan ti kọkọ sọnu nitori laasigbo awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW naa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ EKo tun ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan mii, Akeem Agboola ti apẹle rẹ n jẹ “Okoro” ati ẹlomiran ti orukọ rẹ n jẹ Idowu Johnson, lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu ija igboro to waye logunjọ, oṣu Kinni, ọdun yii.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Kí ló gbé ọ̀gá awakọ̀ èrò méjì, Kunle Poly àti Sego dé àtìmọ́lé ọlọ́pàá l’Eko?

Kunle Poly ati Sego

Oríṣun àwòrán, kunlepoly1 Instagram and Sego

Ẹ̀ka ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri, Rapid Response Squad (RRS), ti mu olori ẹgbẹ́ awakọ meji, NURTW si ahamọ.

Àwọn ọlọpaa RRS ninu atẹjade kan to fisita loju opo Facebook rẹ ni oun mu Abdulazeez Adekunle Lawal ti ọpọ eeyan mọ si Kunle Poly ati Mustapha Adekunle, to tun n jẹ Sego si ahamọ.

Ikọ RRS ni igbesẹ naa ko sẹyin ija igboro to waye ni Isalẹ Eko (Lagos Island) ni ọsẹ to kọjá.

Iroyin sọ pe eeyan kan kú lasiko ija naa, ti awọn onisowo si sa kuro nidi ọjà wọn nigba ti wahala naa fọn ina soju.

Ọwọ ọlọpaa tẹ Kunle Poly ati Sego nibi ipade kan ti wọn n ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni ija igboro naa ṣe waye?

Ọjọbọ, ogunjọ, oṣu Kinni, ni wahala naa waye ni Idumota.

Iroyin sọ pe ariyanjiyan lo kọkọ bẹrẹ laarin awọn ọmọ ẹyin Kunle Poly ati Sego lori ẹni to yẹ ko ma a gba owo ita lọwọ àwọn awakọ ati ọlọkada ni ẹka NURTW ni Ẹyin-Ẹyọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ọjọ ti pẹ ti igun mejeeji ti ma n ja nitori ọrọ garaji.

Iwe iroyin Vanguard jabọ pe Kunle Poly lo n gba owo garaji ni Ẹyin-Ẹyọ ati awọn ibomii, ti Sego si n gba ti inu ọjà Idumota ati abẹ afara Carter.

A gbọ pe Sego fẹ ẹ fi ipa gba ibi ti Kunle Poly n mojuto, lo fa ija to waye ni ọsẹ to kọja.

Ẹnikan lara awọn ọmọ ẹyin Kunle Poly ni iroyin sọ pe o ku lasiko wahala naa.

Ki awọn naa tun to o pada wa gbẹsan ni ọjọ keji.

Eyi to mu ki ọpọ awọn ọmọ ẹyin Sego farapa.

A gbọ pe lati Ereko, Tom Jones, Martins, Oluwole ati awọn agbegbe miran ni Lagos Island ni awọn alatilẹyin Kunle Poly ti wa.

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ati soja la gbọ pe o ba ète ija miran jẹ ni ọjọ Satide.

Kinni alaga ẹgbẹ́ NURTW nipinlẹ Eko, MC Oluomo sọ lori iṣẹlẹ yii?

Lori ija to waye yii, alaga ẹgbẹ́ NURTW nipinlẹ Eko, Ogbẹni Musiliu Akinsanya (MC Oluomo) sọ pe oun ti sọ fun ileesẹ Ọlọpaa pe ki wọn o ṣe iwadii to yẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ninu fidio kan ti ileesẹ iroyin ori ayelujara Goldmynetv fi sita ni MC Oluomo ti sọ ọrọ naa.

O ni ki awọn Ọlọpaa mu gbogbo àwọn eeyan to ba yẹ, ti wn si lọwọ ninu ija igboro ati isekupani naa.

Bakan naa lo sọ pe ilana ẹgbẹ́ ni pe dandan ni fun àwọn alaga garaji kọọkan lati kọ lẹta si olu ile ẹgbẹ́ ti oun ti jẹ alaga fun, lori wahala kankan to ba waye ni ọdọ wọn.

Oluomo ni sugbọn titi di akoko yii, ko si ẹni to fi ọ̀rọ̀ naa to oun leti ninu Kunle Poly ati Sego.

Taa ni Kunle Poly?

Alhaji Adekunle Lawal ni apejẹ orúkọ rẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣù Kẹta, ọdun 1974 ni wọn bi.

Ọmọ bibi Ìsàlẹ̀ Eko ni, nibẹ naa lo si gbe dagba.

Iroyin sọ pe o kawe gboye OND ni ile ẹ̀kọ́ Kwara Poly, ninu ẹka imọ nipa amojuto okoowo lọ́dún 1994.

Lasiko to wa ni ile ẹ̀kọ́ Poly ni awọn ọrẹ rẹ fun ni orúkọ inagijẹ ‘Kunle Poly’.

Akọwe ẹgbẹ́ NURTW ni Idumota lo ti kọkọ fi bẹrẹ isẹ, ko to o di awakọ.

Diẹdiẹ si lo n goke to fi di ọkan pataki lara awọn olori ẹgbẹ́ NURTW ni ipinlẹ Eko.

Lọwọlọwọ, oun ni igbakeji alaga ẹgbẹ́ NURTW nipinlẹ Eko.

Taa ni Sego?

Mustapha Adekunle ni orukọ rẹ, sugbọn inagijẹ rẹ ni Sego.

Sego ni Akapo ẹgbẹ́ NURTW nipinlẹ Eko.

Ko fi bẹẹ si akọsilẹ nipa rẹ lori ayelujara.

Ni bayii, awọn afurasi mejeeji ti wa ni ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Onikan ni Lagos Island.

Ija igboro jẹ nkan to wọpọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ ni awọn ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Ọ̀rọ̀ ipo adari si lo saba ma n fa ija yii, eyi to ma n yọri si òfò ẹ̀mí ati dukia.