Ìjọba Egypt yọ owó ìránwọ́ orí búrẹ́dì, aráàlú yarí

Burẹdi

Oríṣun àwòrán, Reuters

  • Author, Hisham Elmayani
  • Role, BBC News Cairo

Awọn eeyan Cairo, ni Egypt ti bẹrẹ si n to lawọn ileesẹ to n ṣe burẹdi bayii.

Nnkan bi ida meji ninu mẹta idile to wa ni Egypt lo maa n fi burẹdi gbera fun ọpọ ọdun, amọ nnkan ti fẹ maa yatọ bayii.

Fun igba akọkọ ni ọgbọn ọdun ijọba orilẹede naa ti yọ owo iranwo ori burẹdi, eyii to mu ki ounjẹ naa wọn gogo.

Lọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, ni iye owo ti wọn n ta burẹdi wọn si ni ilọpo mẹta.

Ramadan Ali, to jẹ agbẹ ni ariwa Cairo sọ pe “nigba ti ijọa gbowo lori gbogbo nnkan, a sọ pe ko si wahala niwọn igba ti a ṣi le maa ri burẹdi jẹ, amọ ijọba tun ti gba burẹdi naa lọwọ wa bayii.

Ọkunrin naa maa n ra burẹdi ni ₦1.5kobo tẹlẹ latari owo iranwọ ijọba lori burẹdi ti wọn gbe kalẹ lati ọdun 1940.

Awọn burẹdi ti ko ni iranwọ ijọba ni wọn n ta ni ₦19.13kobo ati ₦57.40kobo.

Ramandan sọ pe “ara anfani ti a n jẹ ni rira burẹdi ni iye to kere bẹẹ ti a si n dupẹ lọwọ ijọba.”

Owo iranwọ ori burẹdi naa wa lara awọn owo ti ijọba n na julọ ninu eto iṣuna rẹ paapaa laarin ọdun 2016 si 2020.

Ṣugbọn fun igba akọkọ laarin ọgbọn ọdun, ijọba ti ṣe afikun iye owo burẹdi bo tilẹ jẹ wọn n san owo iranwọ lori rẹ.

Owais Salem, to jẹ olugbe agbegb Upper Egypt sọ pe igbeṣe naa yoo mu ki ọpanlamba iya jẹ ọpọ araalu.

Ẹwẹ, olootu ijọba, Moustafa Madbouly ti sọ pe ijọba ti n ṣe ohun to yẹ lati yanju ipenija awọn araalu lori ọrọ naa.

Aworan ọmọkunrin to gbe burẹdi lọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni Egypt, apẹle orukọ burẹdi ni ‘a’esh’ to n tumọ si igbeaye.

Eyii n tumọ si pe awọn eeyan Egypt fẹran burẹdi pupọ nitori oun ni wọn maa n gbọkan le lọpọ igba.

Eredi ree ti wọn ṣe n binu lori bi ijọba ṣe gbowo le.

Gbogbo igba ti ijọba ba fẹ gbowo lori ounjẹ lawọn eeyan orilẹede naa maa n yari, ti wọn a si tu sita fun ifẹhonuhan.

Nigba ti Aarẹ Anwar Sadat gbe igbesẹ lati fikun owo ounjẹ lọdun 1977 ẹgbẹgbẹrun araalu lo fẹhonuhan laarin igboro ti ọpọ eeyan lagbaye si mọ ifẹhonuha naa si ‘bread uprising’.

Igbesẹ araalu naa mu ki ijọba tu ero rẹ pa lori igbesẹ ọhun.

Amọ lọdun 2021, Aarẹ Abdel Fattah El-Sisi ni o ṣeeṣe ki burẹdi gbowo lori latari bi ọrọ aje ṣe ri kaakiri agbaye.

Egypt jẹ ọkan gboogi lara awọn orilẹede to maa n ko wiiti wọle lati ilẹ okere, eyii to mu ki nnkan tubọ le si nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ilẹ naa ti parọwa sawọn araalu, awọn eeyan naa ni igbesẹ naa yoo fi iya ti ko ṣe e fẹnusọ jẹ awọn.