Ìjọba àpapọ̀, àwọn iléèṣẹ́ aládànìí, fẹnukò lórí owó oṣù tuntun

Àwọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, NLC

Ijọba apapọ ati awọn ileeṣẹ aladanii ti fẹnuko lori iye owo kan naa lati maa san gẹgẹ bi owo to kere ju fun oṣiṣẹ.

Eyi jẹyọ nibi ipade ti igbimọ ti ijọba gbé kalẹ lori owo oṣu tuntun, ṣe pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ, ati ileeṣẹ aladanii.

N62, 000 ni wọn fẹnuko si lati maa san, dipo 60,000 ti wọn kọkọ dabaa rẹ.

Ṣugbọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn ko fẹ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni N250, 000 ni awọn le gba jalẹ, dipo 494,000 Naira ti wọn kọkọ dunadura rẹ.

Igun mejeeji ko fẹnuko lori iye kan titi wọn fi tuka nibi ipade, amọ wọn ṣe ileri lati tẹsiwaju ninu iduna-dura wọn.

Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria ti sọ pe awọn ko l’agbara lati san ẹgbẹrun lọna ọgọta ti ijọba apapọ kọkọ ba ẹgbẹ oṣiṣẹ dunadura.

Ninu ikede kan ti oludari ikede ẹgbẹ wọn, Halima Abubakar, fi sita ni Irọlẹ ọjọ Ẹti ni wọn ti sọ pe bi ọrọ aje ṣe ri lasiko yii yoo mu ko nira lati san owo naa.

Awọn gomina sọ pe loootọ ni afikun owo oṣu waye, “sugbọn owo oṣu nikan lao maa fi owo to ba n wọle fun wa san, lai ṣe iṣẹ idagbasoke kankan”.

Nbi ti ọrọ de duro bayii, a ko le sọ boya ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo tun pada bẹrẹ iyanṣẹlodi.