Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu ìdásílẹ̀ bánkì tí yóò ma a ya àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lówó

Awọn akẹkọọ fasiti

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ti buwọlu ofin kan lati maa ya awọn akẹkọọ lowo fun eto ẹkọ ni fasiti ati awọn ile ẹkọ giga mii.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni ile aṣofin agba mejeeji buwọlu u.

Lẹyin naa ni wọn fi ṣọwọ si Aarẹ Muhammadu Buhari lati buwọlu u fun igba ikẹhin.

Pẹlu ofin tuntun yii, ijọb ayoo da banki kan silẹ lati ma a ṣeto owo yiya naa.

Ofin yii ni akọkọ iru rẹ ni Naijiria.

Olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin, to tun jẹ ẹni to mu aba ofin naa wa, Femi Gbajabiamila, sọ pe Banki fun eto ẹkọ ni Naijiria, yoo ma a ya awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ni Naijiria lowo, lai gba èlé.

Lati ọdun 2019 si ni aba ofin naa ti wa nile aṣofin.

Ti Aarẹ Buhari ba fi fi ọwọ si, ireti wa pe ofin naa yoo mu ki awọn akẹkọọ ri iranlọwọ ati atilẹyin gba lọwọ ijọba fun eto ẹkọ wọn.

Ilana wo ni ofin naa yoo fi ṣiṣẹ?

Ofin eto ẹkọ tuntun yii sọ pe banki ti wọn ba da silẹ yoo ni agbara lati buwọlu, ko si ya awọn akẹkọọ to ba koju osunwọn ni owo.

Bakan naa ni yoo ma a tọpinpin asunwọn ti awọn akẹkọọ fi ya owo, lati mọ bi wọn ṣe n na.

Awọn to ba ya owo naa, yoo bẹrẹ si ni da a pada ni kete ti wọn ba bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lẹyin ẹkọ wọn ati eto agunbanirọ.

Awọn akẹkọọ to fẹ lọ si ile ẹkọ giga ijọba nikan lo lanfaani lati ya owo.

Owo naa yoo wa  fun owo ile ẹkọ, iwe rira, ile gbigbe, ounjẹ ati awọn nkan mii ti akẹkọọ ba nilo.

Laarin ọgbọn ọjọ ti akẹkọọ ba kọwe si banki ni yoo ri owo gba.

Ṣaaju asiko yii, awọn obi nikan ni awọn banki ma n ya ni owo fun eto ẹkọ ọmọ wọn, pẹlu awọn ilana to nira. Bakan naa ni gbese naa kii ṣe ọlọjọ oipẹ.

Aisi owo si ma n mu ki awọn akẹkọọ̀ ti ko ri oluranlọwọ, pa ẹkọ wọn ti, tabi sẹ awọn iṣẹ iwọsi lati le ri owo ile ẹkọ san.

Aṣofin Gbajabiamila sọ pe yoo nira fun akẹkọọ to ba ya owo lati salọ lai san-an pada.

“Idi ni pe akẹkọọ naa gbọdọ jẹ ọmọ ipinlẹ to fẹ ẹ ya lowo, yoo si tun fa oniduro meji kalẹ.