Gómìnà Ademola Adeleke bẹ̀rẹ̀ ìyànsípò tirẹ̀, ẹ wo àwọn mẹ́ta tó kọ́kọ́ ṣ’oríire

  • Author, Yetunde Olugbenga
  • Role, Senior Journalist
Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Twitter

Ni kete ti Gomina tuntun ti ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke gba eku ida lana ti wọn bura wọle fun lo ti yi ọpọlọpọ nnkan to ba nilẹ pada.

Kete to wọ ọfiisi lo ṣe iyansipo gboogi mẹta kan ni ko ju wakati melo kan lọ to ṣe iburawọle.

Ninu atẹjade kan ti Adeleke fi sita lọjọ Aiku ni o ti yan alaga kansu ijọba ibilẹ tẹlẹri nilu Osogbo, Ọgbẹni Kassim Akinleye gẹgẹ bii Ọga agba awọn oṣiṣẹ ni Osun.

Bakan naa lo buwọlu iyansipo Ọgbẹni Teslim Igbalaye gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ naa nigba ti o ya Ọgbẹni Olawale Rasheed gẹgẹ bi Akọwe agba ijọba.
“Gbogbo iyansipo yii gbudọ gberasọ ni waransesa.”

Bakan naa ni iroyin ni gbogbo iyansipo ti gomina ana, Gboyega Oyetola ṣe ni ọjọ perete to ku ko kuro nipo ni Adeleke ti wọgile tori o ni “o lọwọ ibi ninu.”
Adeleke ni Gomina Kẹfa ti yoo jẹ nipinlẹ Osun.

Oyetola gbé èku ìdá sílẹ̀, Ademola Adeleke di gómìnà Osun

Ademola Adeleke

Niṣe ni ariwo n ho yeee bi gomina ti wọn n bura wọle fun, Ademola Adeleke ṣe n ka ọrọ rẹ jade.

Ori papa isere naa kun fọfọ fun ero to fi mọ awọn eekan oloṣelu ati ori ade ti wọn ba wọn pe nibẹ lati lọ yẹ Ademola Adeleke si.

Adeleke n ka agbada soke

Ṣaaju ki Adeleke to bọ sori pepele ni Adajọ ti ṣe iburawọle fun igbakeji rẹ pẹlu iyawo rẹ.

Igbakeji Adeleke ati iyawo rẹ ṣe iburawọle

Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ ati agba oloṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lo wa nibi ibura wọle naa.

Awọn eekan ẹgbẹ PDP
Awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP

Àwòrán Davido, àwọn èèkàn níbi tí ètò ìbúrawọlé Ademola Adeleke ti ń wáyé

Eto Iburawole

Olu ilu Osogbo nipinle Osun ti gbe awo titun wo saaju ayeye ibura fún Gomina tuntun ti won dibo yan ọjọ kerindinlogun osu keje odun 2022, Seneto Ademola Adeleke to n waye ni oni ojo ketadinlogbon osù kọkànlá.

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ gbajugbaja ọdọ olorin, David Adeleke to padanu ọmọ rẹ Ifeanyi laipẹ yii pe yoo le ba ẹbi wọn pe nibi eto iburawọle aburo baba rẹ ti wọn sunmọ ara wọn timọ timọ. Akọroyin BBC Yoruba foju gaani rẹ nibẹ.

Davido atawọn eekan ilu
Davido

Ni papa iṣere Osogbo stadium, nibi ayẹyẹ ibura fún Gomina tuntun atiwaye ni akoroyin bbc news yoruba ti ri pe gbogbo eto ni ṣepe.

Iburawọle Ademola Adeleke
Iburawọle Ademola Adeleke
Adajọ ti yoo burawọle fun Adeleke

Orisiirisii posita Sen Ademola Adeleke ati Igbakeji Gomina Omoba Kola Adewusi ni won fi gbà gbogbo papa isere Osogbo káàkiri.

Iburawọle Ademola Adeleke
Eto iburawọle Adeleke

Nibayi, eto aabo ti ibi pápá isere Osogbo wa ni pipe pẹlu awọn ọlọpa ti o ni ihamọra ni kikun ti n ṣọ ibi ti ayẹyẹ naa o ti wáyé.

Eto Iburawọle

Ọjọ́ kò! Ademola Jackson Adeleke yóò gbàjọba ìpínlẹ̀ Osun

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adelek/Twitter

Gẹgẹ bi gbogbo eto ti wọn la kalẹ lati ibẹrẹ ọsẹ yii ṣe ti n lọ ni mẹlọ mẹlọ, oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn Oṣu Kọkanla ọdun 20022 ni aṣekagba to si tun jẹ ọjọ ti wọn yoo bura wọle fun gomina wọn tuntun, Ademola, Nurudeen Jackson Adeleke.

Bo tilẹ jẹ ke ọwẹ diẹ sẹyin yii ko fi bẹẹ rọgbọ tori gbogbo ẹjọ ti Gomina Oyetola pe Adeleke to si wọ ọ lọ ile ẹjọ, ọjọ naa tun pada ko lonii.

Lara awọn nnkan to ti ṣẹlẹ ṣaaju ọjọ yii ni:

Ile ẹjọ wọgile idibo ijọba ibilẹ ti Oyetola ṣagbatẹru rẹ

Adeleke ati Oyetola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ́ giga ijọba apapọ to wa nílùú Osogbo, nipinlẹ Osun, ti wọgile eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni oṣu Kọkanla.

Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹwaa, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ naa ṣe eto idibo ọhun.

Adajọ Nathaniel Ayo-Emmanuel, sọ ninu idajọ rẹ pe eto idibo naa tako ofin idibo, abala kọkandinlọgbọn ati abala kejilelọgbọn, ti ọdun 2022.

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, lo pe ẹjọ́ tako idibo naa, to si ni ki ile ẹjọ́ pàṣẹ fun ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun OSIEC, lati má ṣe eto idibo kankan.

Oyetola yan akọ̀wé àgbà 30, Adeleke fárígá pé kó jọ ọ́ rárá!

Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti kede pe oun ti buwọlu iyansipo awọn osisẹ ijọba toto ọgbọn niye gẹgẹ akọwe agba fun awọn ẹka ijọba ni o ku ọjọ mẹta ti yoo fi po silẹ gẹgẹ gomina ipinlẹ naa.

Orukọ awọn akọwe ọhun lo wa ni atẹjade ti akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Osun, Dokita Festus Oyebade buwọlu fun awọn akọroyin lana.

Oyetola lo lulẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to waye ninu oṣu keje, ti Ademola Adeleke lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP si gbe igba aroke.

Sugbọn kete ti ijọba ipinlẹ gbe ikede naa jade ni Gomina tuntun ti ilu dibo yan, Ademole Adeleke fesi pada ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed bu wọlu to si tako igbesẹ naa.

Ọwọ́ ta ni ìwé ẹ̀rí Adeleke wà? Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ láàrin Adeleke àti Oyetola ní Tribunal

Ademola Adeleke

Ajọ eleto idibo, INEC, ti sọ pe awọn iwe ẹri gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ko si lọwọ oun mọ.

Alaga ajọ naa nipinlẹ Osun, Ọmọwe Mutiu Agboke, sọ nile ẹjọ to n gbọ ẹsun awuyewuye to waye lẹyin idibo gomina ipinlẹ naa, lọjọ Iṣẹgun pe oun ko ni Form CF 001 ti Adeleke lo lọdun 2018 lọwọ mọ.

Ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun INEC, pe ko mu fọọmu naa wa sile ẹjọ, lẹyin ti olupẹjọ, Gomina Gboyega Oyetola bẹ ile ẹjọ lati ṣe bẹẹ.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni Gomina Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fi iwe ẹsun naa ranṣẹ sile ẹjọ.

Form CF 001 ni fọọmu ti oludije fi forukọ silẹ lati dije, ati awọn iwe ẹri ti Adeleke fun INEC lọdun 2018.

Adeleke fọ̀rọ̀ ìdágbére ńlá ránṣẹ́ sí Oyetola tó ń kó ẹrù rẹ̀ kúrò nílé ìjọba Osun

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Gomina to ti fẹ kogba wọle, Gboyega Oyetola pe ko gba kamu pe o ti lulẹ ninu eto idibo gomina to waye ni oṣu Keje, pe ko si simi ariwo ni pipa.

Agbẹnusọ Adeleke, Olawale Rasheed ninu atẹjade to fi ransẹ si Oyetola lẹyin to kede pe oun yoo gba ẹtọ oun, ni pe ko si ẹtọ kankan to fẹ gba lọwọ Adeleke nitori gbogbo ọna ni o fi fi idi rẹ janlẹ ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ Osun.

O ni erongba buburu ni Oyetola ni si awọn eeyan ipinlẹ Osun latari bi o ṣe n fi irọ ati ailotọ ṣe ijọba rẹ.

Adeleke ni kete ti Oyetola ri pe oun ti lulẹ ni o ti bẹrẹ si ni maa ṣe owo ipinlẹ naa basubasu sugbọn ti ile ẹjọ si ti tu ọpọlọpọ irọ ti Oyetola pa fun awọn eeyan.

PDP Osun da eto duro tori iku ọmọ Davido

Bi ẹ ko ba gbagbe, lara ajọyọ ti gbajugbaja olorin nni Davido n ṣe nigba ti ibura wọle ẹgbọn rẹ Adeleke sunmọle naa ni pe awọn yoo jọ wa nibẹ ni.

Ko pẹ rẹ ni ọlọjọ de ti o mu Ifeanyi ọmọ Davido lọ.

Eyi lo faa ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun ṣe daro iku ọmọ naa ti wọn si dawọ eto ti o yẹ ki wọn ṣe lọsẹ naa duro.