Gbogbo ìbéèrè tóo ní lọ́kàn nípa dída omira obìnrin lásìkò ìbálòpọ̀, ìdáhùn rèé

Obinrin to la idi silẹ

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

… to fi mọ boo ṣe le ṣe e ati idi ti wiwo awọn eeyan to n ṣe e lọwọ lori ayelujara ṣe lodi si ofin.

Nibo ni dídamira ti wa? Ṣe itọ ni? Atipe bawo ni mo ṣe le jẹ ko jade? Itumọ eyi ni bi nkan bii omi ṣe maa n jade labẹ obinrin lasiko ti ara r ba ti dide daadaa ṣaaju diẹ abi nigba ibalopọ.

Igba akọkọ ti Gilly ni ọdun mọkanlelogoji pọ omira yii jade, o mu u doke tete gidi gan ni. “Mo gan pa pẹlu iyalẹnu; mo wa riri, afi bii itusilẹ. “Mo ya fọto ibi to tutu naa lati fi da ara mi loju pe o ṣẹlẹ si mi”.

Aworan

Oríṣun àwòrán, ISTOCK / BBC THREE

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ni ti Tash ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, o tun pọ to si n wo pe ṣe ko ni ba kapẹẹti jẹ. “Nkan iṣere ibalopọ mi ni mo n lo ti mo si joko fẹyin ti ninu yara mi tori bi eeyan kan yoo ba fẹ wọle, nigba ti mo si dede ri i ti o fẹ maa jade ẹru ti ba mi. Imọlara to ṣe ju ti mo ri niyii; ẹru ba mi diẹ oju si ti mi, mi o mọ ohun to n ṣẹlẹ. Mo ba sare nu ori rọọgi mo si sare wa itumọ ohun to ṣẹlẹ lori ayelujara”.

A mọ pe lati ọjọ pipẹ, awọn obinrin kan le da omira iye kan ninu nkan ọmọbinrin wọn lasiko ibalopọ tabi nigba ti ara wọn ba dide.

Ẹwẹ, ko ṣi tii ye pẹlu iwadii iye awa to maa n damira. Iwadii igbalode ti fihan pe iṣẹlẹ yii maa n waye bakan bakan nibikibi laarin ida mẹwaa si mẹrinlelaadọta awọn obinrin.

Bakan naa iwadii kan lọdun 2013 fihan laarin obinrin ọọdurun le ogun to kopa pe iye idamira to n jade lee to laarin iwọn 0.3ml si o le ni 150ml. Eyi ni nkan bii kp maa kan di diẹ tabi titi ti yoo fi to idaji ife.

Tori eyi, o jẹ akọle nla to n fa oju awọn eeyan mọra plu bi iwoye wa ṣe n pọ sii nipa bi ara obinrin ṣe n dagba.

Oya jẹ ka gba ibẹ wọle

Aworan

Oríṣun àwòrán, ISTOCK / BBC THREE

Ki wa ni nkan bii omi to maa n jade lasiko idamira ati pe ibo lo ti n wa?

Ọkan lara awọn ibeere to maa n jẹy ni pe boya itọ ni omi to maa n jade yii. Bẹẹ si ni awọn iwadi kan sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ itọ.

Lọdun 2014, wọn ni ki awọn obinrin kan l si ile itọ ni asiko diẹ ṣaaju ibalopọ ki wọn si ṣe ayẹwo ultrasound lati fi aridaju han pe ofo ni ile itọ wn wa. Lẹyin ti ara awọn obinrin naa ti wa lọna gidi, wọn tun ṣe ayẹwo ẹlẹẹkeji eyi to fihan pe ile itọ wn ti kun pada lootọ. Lakotan wọn ṣe ayẹwo ẹlẹẹkẹta nigba ti wọn damira tan to si ṣafihan pe ile itọ wọn tun ti ṣofo. Eyi n s pe boya omi ti wọn da wa lati ibi to ṣeeṣe ko jẹ itọ (bo tilẹ jẹ diẹ).

“Didamira ṣeeṣe ko wa latinu ile itọ paapaa tori ko si ibo miran lagbegbe nkan ọmọbinrin to lee gbe iye omi bẹyẹn duro tabi pọ ọ jade pẹlu iru agbara naa. Apoogun Abass Kanani lo s bẹẹ. “Lasiko ti ara maa n dide fun ibalopọ, egungun ara a fara balẹ a si jẹ ko nira lati gba itọ mu torinaa a tu u jade latinu ile itọ.

Sibẹ sibẹ, awọn iwadii pupọ mii fihan pe ko dara lati dede woye pe bi didamira kan ṣe n ṣẹlẹ niyii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Amọ ni ilana Sayẹnsi, ibẹru ki wọn ma ri wọn pe wọn tọ sara lawọn obinrin mii fi n fa sẹyin lati damira, ayafi bi nkan idiwọ mii ba wa.

Omi to n jade jọ bi eyi to mọ gaara, kii ṣe awọ rusurusu ko si run tabi ri lnu bii itọ”. Gẹgẹ bii nọọsi tẹlẹri mo ti ni iriri pẹlu ọpọlọpọ itọ mi o si ro pe nkankan naa ni!”.

Ni ida keji, ọpọlọpọ obinrin to damira gba pe “ọpọ igba ni mo ti damira ti mo ṣi tun maa nilo lati tọ lẹyin naa,”. “Omira mi ko ni awọ kankan”.

Awọn onimọ Sayẹnsi tilẹ tun sọ pe didamira ṣeeṣe ko ni idi mii to ju igbadun nikan lọ: lati mu titọ rọrun ko si ma dun obinrin lẹyin ibalopọ.

Gbogbo ohun ti ibaa wu ko jẹ ẹwẹ, bi eeyan ba damira, ohun to da jade ati boya o ni anfani tabi ko ni – ki lo ṣe pataki ninu gbogbo iyẹn teeyan ba ti gbadun rẹ?

Mo gba. Mo fẹ dan an wo! Amọ bawo?

Aworan

Oríṣun àwòrán, iStock/BBC Three

Ọpọlọpọ obinrin to maa n damira sọ pe nkan to gbe awọn debẹ ni bi apa inu nkan ọmọbinrin wn to n j G-Spot ṣe ṣe – eyi ni ibi kan to to centimetre marun un si mẹjọ ninu nkan ọmọbinrin.

Ọwọ iwaju lo wa(lọna ibi idodo rẹ kii ṣe lẹyin rẹ) to si maa n da bii eyi to tẹ́ lọwọ ju ẹya ara to yi i ka lọ.

Wọn ti wa wo G-Spot gẹgẹ bii agbegbe ibi ti eeyan ti le ṣe ayunlọ ayunbọ inu nkan ọmọbinrin pẹlu koko ori nkan ọmọbinrin.

“Mo maa n jẹ ki ololufẹ mi fi ika rẹ ra G-Spot mi ti yoo si maa mu mi pee wa lati fọwọ kan an sii pẹlu agbara. Saffron ẹni ọdun 34 lo sọ bẹẹ.

“Nkan iṣere ibalopọ maa n mu mi ni iriri kan naa lọna to rọrun. Ti mo ba ti tẹsiwaju pẹlu rẹ titi ara mi fi wa lọna gidi, o lee mu mi damira”. Daphne ẹni ọdun mẹtalelogun lo sọ bẹẹ.

Ọna pataki mii to le gba damira

Aworan

Oríṣun àwòrán, iStock/BBC Three

Kọkọ mu aṣọ inura towẹẹli silẹ na. Tori ọtọọtọ ni iṣẹda wa, ranti pe kii ṣe gbogbo eeyan ni yoo fẹran ọna yii lati mu ara wa lọna.

Koda awa kan ri wiwa G-Spot gẹgẹ bi eyi to nira – ṣaa ti rii daju pe ohun ti yoo mu iwọ gbadun ara r lo n wa, kii ṣe tori pe o kan nilo rẹ. Ati pe daw duro too ba ti ri i pe oo gbadun rẹ rara.

Ero ọtọ

Mo ti pade awọn obinrin to jẹ wipe oju maa n ti wọn gan pe eyi n ṣẹlẹ si wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ro o wipe ko tọ o si le ti ololufẹ wọn danu.

Ẹru n ba wọn pe ololufẹ wọn a ro pe awọn tọ sara ni to si n fa itiju nla.

Ẹkọ pataki?

Ko sohun to buru ninu keeyan damira ko si sohun to buru ninu keeyan ma damira. Ẹni to da ko tumọ si pe o san tabi pe o buru ju ẹnikeji lọ. Jẹ ki kan rẹ ṣi silẹ lati gbadun ara rẹ. Kii ṣe ọranyan kii sii ṣe alebu