Gbogbo ẹ̀yin Mùsùlùmí Yorùbá tí ẹ ń pè fún Yorùbá Nation ẹ lọ tún èrò yín pa – Ishaq Akintola

Gbogbo ẹyin Musulùmí Yorùbá tí ẹ ń pè fún Yorùbá Nation ẹ lọ tún èrò yin pa- Ishaq Akintola

Oríṣun àwòrán, Ishaq Akintola

Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ mùsùlùmí (MURIC) sọ pé àwọn kò faramọ́ kí ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá, Afẹ́nifẹ́re máá fi Sunday Igboho wé Anọ́bì Mohammed nínú kùránì.

Lọ́jọ́ Ajé ni ẹgbẹ́ Afẹ́nifére ti sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé kò sí nǹkan to burú nínú bí Sunday Adeyemo ṣe sa kúrò ni Nàìjíría.

Wọ́n ni báyìí náà ni Mose ṣe sá fún Pharaoh nilẹ̀ Egypt ti Anóbi Muhammed náà si sákúrò ní ìlú rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń ṣe inúnibíní síi.

Igboho ń kójú ìjẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ ni Cour De’appal tii ṣe ile ẹjọ wọn ni Cotonou lẹ́yin ti wọ́n múu ni pápákọ̀ òfurufú Cardinal Bernardin ni orílẹ̀-èdè Benin.

Afẹ́nifẹ́re ní àwọn ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ń wá a lẹ́yìn tí wọ́n ya bo ilé rẹ̀ nílùú Ibadan, èyí sì ló jẹ́ kí ó na pápá bora.

Lọ́jọ́ Iṣẹ́gun ni adarí ẹgbẹ́ MURIC ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Akintola fi síta nínú àtẹjade kan pé, Ànọ́bì Muhammed láti ilẹ ló ti máa n lọ láti ìlú kan sí òmíràn, èyí sì yàtọ̀ sí nǹkan ti Igboho ń kojú.

“Èyí kò ṣee faramọ́ rárá. Àbùmọ́ ọ̀rọ̀ lásán ni, ọ̀rọ̀ ti afẹ́nifẹ́re sọ jọ èyí tí wọ́n fẹ́ fi ru ibínú ẹlòmííràn sókè, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ti kò mú ọpọlọ dání tí ó sì dàbí yíyẹ̀yẹ́ ẹni, gẹ́gẹ́ bi Akintola ṣe sọ.

” Àwọn nǹkan tí ó kojú àrìnkiri Ànọ́bì Muhammad ni 622 C.E sí Madinah yàtọ̀ gédégédé sí nǹkan tó mú kí Igboho sálọ sí Benin Republic nínú oṣù keje ọdún 2021.

Adarí MURIC sọ pé gbogbo Musulumi tó jẹ́ Yorùba tí wọ́n sì ń pè fún Yorùbá Nation, ó ṣe pàtàkì láti lọ ṣe àtúnṣe.

Ó ní tí àwọn músùlùmí tó bá kọ̀ láti dẹyin láti máá pè fún Yorùbá Nation tabí Odudujwa Republic, lẹ́yìn ti Afénifẹ́re tí bú ẹnu àtẹ́ lu ànọ́bí Muhammad, ìdá ń dúro de ẹni náà lọ́ja àgbénde Alikiyamọ.

Ẹwẹ, ẹgbẹ Afenifere ti pada fi alaye ọrọ sita pe awọn ko sọ bẹẹ rara ni ọna ti awọn eeyan fi n gbee gẹgẹ pe Sunday Igboho dabii Anọbi Mohammed.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ