Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, “Doughnut”, ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin

Awọn to n gba abẹrẹ Covid-19

Oríṣun àwòrán, Chip Somodevilla

Orisi ọna ni awọn ijọba kaakiri agbaye n gba lati ri pe awọn ara ilu gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Yatọ si ipolongo ati ọna mii bi ka ni kawọn olori ẹlẹsin parọwa si araalu, ọna mii wo lẹyin tun mọ?

Bi ẹ ko baa ti gbọ tẹlẹ, ki a maa fasiko yi fi to yin leti wi pe ijọba orileede Amẹrika n gba awọn eeyan niyanju lati gba abẹrẹ Covid-19 nipa fifun wọn ni ẹbun iwuri.

Ninu awọn ẹbun yi la ti ri ọti, doughnut ati ipin idokowo ifowopamọ, savings bonds.

Ipanu Doughnut

Igbiyanju yi la gbọ gbe pe wọn se pẹlu ajọsepọ awọn ileesẹ kọọkan lọna ati mu ki awọn eeyan gba abẹrẹ Covid-19.

Biden sọ fun awọn akọroyin nile ijọba White House pe ”A mọ wi pe ọkẹ aimọye awọn eeyan Amẹrika lo nilo ka gba wọn ni iyanju ki wọn to le gba abẹrẹ yi”.

Iye awọn to ti gba abẹrẹ Covid-19 nilẹ naa si kere.

Nkan bi ida mẹrindinlọgọta ninu ida ọgọrun awọn agbalagba to ja si miliọnu marundinlaadọjọ lo sẹsẹ gba ẹyọ kan ninu iye abẹrẹ ajẹsara to yẹ ki wọn gba.

Nitori eyi, awọn alasẹ nijọba apapọ, yi ipinlẹ n pawọpọ pọ pẹlu awọn onileesẹ to n ta oogun, ile ounjẹ, ileesẹ to n pọn ọti ati awọn ile itaja igbalode to fi mọ awọn ẹgbẹ ere idaraya lati se koriya fawọn araalu.

Ni ipinlẹ New Jersey, Gomina wọn Phil Murphy se ifilọlẹ eto kan to pe ni ”gba abẹrẹ kan ka fi ọti taa ọ lọrẹ”.

Awọn to n mu ọti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O salaye loju opo Twitter rẹ pe “araalu kankan to ba gba abẹrẹ ajẹsara rẹ ni osu Karun yi to si mu kaadi abẹrẹ naa lọ si ileesẹ to n pọn ọti taa jọ lajọsepọ, ẹni naa yoo gba ọti ọfẹ”

Amọ sa awọn araalu ti ọjọ ori wọn baa ti kọja ọdun mejilelogun nikan lo le jẹ anfaani ọti ọfẹ yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oun nikan kọ, koda Gomina Ned Lamont ti ipinlẹ Connecticut naa kede ọti ọfẹ lawọn ile olounjẹ to pawọpọ ninu eto yi.

Bẹẹ naa ni ọrọ ri ni Washington nibi ti Mayor wọn, Muriel Bowser ni kawọn eeyan tu yaya jade wa mu ọti sawọn lọrun lopin igba ti wọn ba ti gba abẹrẹ ajẹsara wọn ni ibudo osere John .F.Kennedy

Ko tan sibẹ, Gomina Maryland Larry Hogan ni awọn osisẹ ijọba to ba gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 yoo gba ẹbun ọgọrun dọla.

Owo Dollar ati ogun Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yatọ si eyi, wọn gbọdọ setan lati gba abẹrẹ alekun tabi eyikeyi ti ajọ to n gbogun ti aisan ba la kalẹ bi bẹẹ́ kọ wọn yoo da owo ọgọrun dọla ti wọn ba fun wọn pada.

Hogan salaye pe ”awọn koriya bayi jẹ ọna lati jẹ kawọn eeyan mọ pataki abẹrẹ ajẹsara, a si rọ awọn ileesẹ kaakiri ipinlẹ yi lati se koriya fawọn osisẹ wọn naa”

Laarin awọn agbalagba ilẹ Amẹrika, ida mọkalelọgọta lo sọ pe awọn ti gba abẹrẹ tabi tawọn n gbero lati se bẹ.

Ida mẹtadinlogun wọn lo n woye lati ri bi nkan ba ti se lọ ki wọn to gba.

Ida mẹtala ni akọsilẹ wa pe wọn ni awọn ko ni gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 rara.