Fídíò, Wo iléeṣẹ́ tó ń pa àlòkù táyà dà sí èròjà aláràbarà fún ẹ̀ṣọ́ ilé àti ara, Duration 8,11

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Recycled Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Ni ọpọlọpọ igba ni awọn eroja ti a ko lo mọ maa n fa idọti sinu ile, ti a si maa n lọ da wọn nu si ori akitan lai mọ pe ọpọ wọn si le pada wulo fun wa.

Iru awọn eroja bayii ni Taya ọkọ ti ko dara mọ eyi ta saba maa n ko da sori akitan.

Amọ ni ilu Ibadan, ileesẹ kan ti wa to n lo eroja taya aloku yii lati fi dabira pada sinu ile, eyi ti yoo mu ki ile rẹwa si, ti yoo si dun wo.

Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo si ile isẹ naa, a ri ọpọ eroja alaranbara ti wọn n fi awọn aloku taya yii se.

Ki ni wọ̀n n fi Taya aloku se?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, oludari ileesẹ naa, Ifedolapo Runsewe salaye pe awọn taya aloku ti awọn eeyan ko naani yii, ni awọn maa n lo fun ọsọ ile.

Lara awọn eroja ẹsọ ile ti wọn n se nibẹ ni Tiles, eyiun ọsọ alẹmọlẹ ti wọn fi n buyi kun ayika inu ile, Bata alawọ alalopẹ, ẹni atẹẹka (Rubber Mat).

Awọn nnkan yoku ti wọn tun n fi aloku taya se ni onka awọn ọmọ ni ABD ati isiro (Alphabet), oniruuru aworan bii olododo ati firemu fun fọto ara ogiri.

Awọn ẹsọ mii ti wọn tun n lo aloku taya fun ni aburada, labalaba ati igi keresi.

Bawo ni wọn se n pa aloku taya da fun ẹsọ ile?

Ọ́kan lara awọn agba osisẹ nileeọ̀ẹ naa salaye pe oniruuru ẹrọ to n lọ taya ni awọn ni lati fi se isẹ naa.

O ni awọn yoo kọkọ yọ irin to wa ni ara taya na, ko le rọrun fun awọn ẹrọ naa lati lọ taya naa.

Lẹyin naa ni awọn yoo wa fi ẹrọ lọ awọn taya yiii ni oniruuru ọna tawọn ba n fẹ, omiran le kuna bii elubọ nigba ti omiran le ma kunna rara, ko si tobi diẹ.

O ni awọn taya ti wn lọ, to kunna bi elubọ naa ni awọn fi n se oniruuru aworan fun ẹsọ ile ati ilo awọn ọmọde fun onka nile ẹkọ.

Amọ awọn taya ti wọn lọ, ti ko kunnna ni wọn n lo lati fi se bata, ẹni atẹẹka onirọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ọpọ ipenija to n koju ileesẹ naa ree:

Nigba to n salaye ọpọ ipenija to n koju ileesẹ aserọba naa, Runsewe ni aisi ina ọba jẹ isoro nla kan gboogi to n koju ileesẹ́ naa, to si jẹ pe ẹrọ amunawa ti awọn n ra epo si ni awọn maa n lo lọpọ igba.

Isoro miran to tun n koju ileesẹ alotaya naa ni aisi eto aabo to yẹ, ka maa sẹsẹ sọ ti pasipaarọ owo naira ilẹ wa ti ko rọgbọ fawọn ileesẹ lati sisẹ.

Ọpọ Anfaani ti ileesẹ naa n se fun ilu:

Runsewe tẹ siwaju pe ileesẹ awọn n pese isẹ fawọn araalu, ti gbogbo wọn jẹ ọmọ Naijiria, lai si ajoji kankan laarin wọn.

O ni osisẹ mẹrin pere lawọn fi bẹrẹ nileesẹ naa amọ nibayii, gbogbo awọn osisẹ naa ti di aadọjọ niye.

Ko tan sibẹ o, ọpọ awọn eeyan to n ba wọn sa taya kiri adugbo,lo n gba owo lọwọ awọn, ti awọn si tun pese isẹ fun wọn.

Bakan naa lo ni awọn n mu ki ayika wa mọ tonitoni nipa sisa awọn aloku taya to jẹ idọti laarin adugbo, lati fi se ẹsọ ile ati ara.

Lakotan, o ni igbesẹ ti awọn n gbe yii ti mu ki asa sisun taya dinkun lawujọ nitori sisun taya lewu fun agọ ara wa.

Afojusun wọn fun ọjọ ọla:

Adari ileesẹ to n lo aloku taya naa wa salaye pe afojusun ileesẹ to n lo taya naa ni lati maa lo irin pẹlu.

O ni gbogbo awọn eroja onirin ti awọn eeyan ba danu ni awọn fẹ maa pa lara da lati fi se awọn ẹsọ ile ati ara lorisirisi.

Bakan naa lo ni awọn yoo tun maa sa ike aloku kiri ori akitan to fi mọ ounjẹ ajẹku lati fi pese eroja lorisirisi.