Fídíò, Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle, Duration 6,17

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Mo maa n mọ lara mi pe ẹmi mii (Eṣu) maa n ba le mi ti mo ba wa n’ile ifa”.

Inu ẹsin igbagbọ awọn ọmọlẹyin Kristi koda inu ijọ Deeper Life ni wọn bi Oluwo Olakunle si amọ to sọ irinajo rẹ wọ inu didi Onifa ati ogbontarigi Babalawo fun BBC Yoruba.

“Mo ti ba Eṣu rin, mo ti ba Eṣu jẹ, mo ti ba Eṣu mu, mo si rii wipe olootọ aye yii ni Eṣu. Kò sí ọrọ tí wọn ń sọ ní Ṣọọṣì tó ń wọ etí mi mọ, mo kàn lọ sí ilé ìjọsìn torí àwọn òbí mi ni”.

Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni Babalwawo to mọ iṣẹ doju rẹ doju ami yii bo tilẹ jẹ pe o sọ fun wa pe awọn obi oun jẹ ọmọ ijọ onigbagbọ Deeper Life pọnbele ti wọn n ṣe ẹsin igbagbọ tọkantọkan.

Ki wa lo de, ba wo lo ṣe rin in to gbe igba Babalawo sori?

Oluwo Olawole Olakunle ni awọn ẹlẹsin ifa kan lo jẹ iwuri fun oun ti ẹsin naa fi wu u. Wọn n gbe lẹgbẹ ile wọn.

“Mi ò kí ń ṣe Oníṣègùn, ògbólógbòó Babaláwo akẹyọ ni mí, Onífá ni mí, Ẹlẹbọ ni mí”.

Oluwo yii ni awọn obi oun kọ oun lọmọ nigba to yan ọna ẹsin ifa. O ni ipa ati erongba oun gẹgẹ bi ọdọ Babalawo ni lati ran awọn ọdọ atawọn iran to ṣẹṣẹ n bọ lati pada si ọna ipilẹ aṣa ati iṣẹṣe awọn baba nla baba wọn gẹgẹ bi ọmọ Afirika.

O ni iṣẹ Babalawo jẹ eyi to bu iyi kun eeyan to wuu ki gbogbo eeyan koda to fi mọ awọn obi oun mọ ki wọn si gba eyi gbọ lọjọ kan.