Fídíò, ‘Ojú olójú ni wọ́n fi sọ mí di ẹni tó n ríran lẹ́yìn tí mó fọ́jú fún ọdún méje’, Duration 3,07

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oju ni ọba ara. “Bi ọlọjọ ba dé, oju ni nkankan to kọkọ maa yọ, beeyan ba ṣe alaisi, laarin wakati mejidinlogun ti eeyan ba ti ku, o ni iṣẹ taa le ṣe sii lati da oju naa si fun ẹlomiran”.

Ohun ti oloyinbo n pe ni Corneal blindness jẹ iru ifọju to maa n de ba oju nipa ki iran bẹrẹ si ni dinku diẹdiẹ nitori aisan to n jẹ cornea.

Onimọ nipa iṣegun ati ayẹwo oju ba BBC Yoruba sọrọ pe awọn eroja to ṣe pataki kan wa ninu oju ti orukọ rẹ n jẹ Corneals to si jẹ wipe eeyan o gbudọ ṣe aṣiṣe to lee mu ki o da iṣẹ silẹ.

Aisan cornea ọhun ni aisan kẹrin to wọpọ ju lagbaye eyi to si jẹ pe oun lo fa nkan bii ida marun oju fifọ to ti ṣẹlẹ.

Ni ilu Eko ni BBC Yoruba ti ṣabẹwo si ile iwosan oju kan ti wọn ti maa n gba oju ti eeyan ba yọnda lati da oju ẹlomiran to ni iṣoro ifọju latari aisan cornea pada.

Ẹwẹ, bii ti ọpọlọpọ ifẹ ti awọn eeyan to ba wu maa n ni si fifun ni ni awọn ẹya ara bii kindinrin, ẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, fifunni ni oju yii kii ṣe gbogbo eeyan lo tẹwọ gba lati maa ṣe e.

Amọ Eleduwa ṣe ti Emma Akana oṣiṣẹfẹyinti amojuẹrọ to sọ iriri rẹ gẹgẹ bo ṣe jẹ anfani ifuni ni ẹynju lẹyin igba to ti kọkọ fọ loju latari aisan cornea.

“Nigba naa mo fọju patapata, mi o le ri eeyan kankan amọ lẹyin iṣẹ abẹ naa ti dokita ni oun yoo gbe “cornea” mii si oju mi, iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu lo jẹ fun mi. Bi mo ṣe bọ si aye tuntun niyẹn o!”.

Bakan naa, awọn akọṣẹmọṣẹ ni ileeṣẹ naa sọ ọna ti awọn eeyan lee gba jọwọ oju wọn ti wọn ko ba nilo mọ fun iwulo ti ẹlomiran.