Fídíò, ‘N10 la ṣì ń ta Ọṣẹ Aboke látayédáyé! Òòṣà ni àrùn ìgbóná, gbogbo yín lẹ sì níi lára, èèwọ̀ rẹ̀ rèé o’, Duration 4,04

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Oṣẹ Aboke jẹ ọṣẹ iṣẹmbaye ti awọn ara ilu Aboke ṣi n wari fun titi di oni fun ipa pataki to n ko ninu ilera awọn eniyan.

Oloye Fasola Famapowa to jẹ Oloye Aboke ti ilu Ibadan ati olori ẹbi awọn Aboke to n gun ọṣẹ naa ni arun bii igbona atawọn mii to fara pẹ ẹ ni ọṣẹ yii le wosan.

Ara ile Aboke gbe itan kalẹ fun BBC Yoruba pe lasiko ogun to bẹ silẹ laarin awọn ẹya Tapa ati Yoruba nigba naa lọhun.

Oloye Fasola ni Ogun awọn Ebira lawọn kọkọ koju nilu awọn ki ti Fulani to bẹrẹ. O ni “nigba ti ilẹ yoo fi mọ awọn Igbira, wọn o mọ ohun ti wọn ṣe mọ”.

Wọn da igbona si awọn ẹya Yoruba lara amọ ọṣẹ naa lo jẹ angẹli ti Eledua ran si wọn.

Ẹwẹ, pẹlu ohun ti a ri, ọṣẹ naa ṣi wa laye titi di oni to si n ṣe bẹbẹ bii tatijọ.

Idile Aboke ti a kan si ni awn ni lọrun fi ṣiṣe irubọ ati gigun ọṣẹ naa pọ ti wọn yoo tun gbadura si Oke Ibadan to jẹ apata giga kan ni ilu Ibadan.

Wọn ṣi nigbagbọ pe ọṣẹ naa ṣi n wo aruin igbona titi doni koda, wọn lee tun gun ọṣẹ naa pọ mọ awọn nkan mii fun eeyan fun oniruuru ojutuu ni ilana ibilẹ ti wọn ba n wa si iṣoro wọn.