Fídíò, Kí ló dé tí ọba méjì fi ń dé àdé nílùú Ikere Ekiti?, Duration 8,50

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Yoruba ni agbo meji ko le mu omi ninu koto kan soso, bẹẹ si ni ọba meji ko le wa ninu aafin kan soso.

Amọ awọn ilu kan wa nilẹ Yoruba to j pe awọn ọba meji tabi ju bẹẹ lọ lo n pasẹ ninu ilu kan soso.

Iru ilu bẹẹ ni ilu Ikere Ekiti to wa ni ipinlẹ Ekiti, nibi ti awọn ọba meji ti n figa gbaga lori ẹni ti asẹ ilu naa tọ si.

Awọn ọba mejeeji naa ni Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ ti Ikere ati Ògògà ti ilu Ikere.

Koda ọrọ naa ti wa niwaju ile ẹjọ bayii, ti ọpọ eeyan si n beere pe bawo lo se jẹ ti agbo meji se n mu omi ninu koto kan soso nilu ilu kan.

Idi ree ti BBC Yoruba se morile ilu Ikere Ekiti lati mọ ọna ti awọn oriade mejeeji n gba dari ilu naa, ti ko fi si rogbodiyan.

Bakan naa la tun fẹ mọ itan to rọ mọ bi awọn ọba alaye mejeeji se de ori itẹ ati bi wọn se mọ odiwọn ilẹ ibi ti wn n se akoso le lori.

Ilu Ikere ti ni Ọba, ki Ogoga to wọ ilu wa – Olukere:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olukere ti Ikere, Ọba Ayodele Obasanyin salaye pe ilu Ikere ti wa, ki Ogoga to wọ ilu naa wa rara.

O ni Olukere kẹfa lo wa lori oye nigba ti Ogoga de aarin wa nilu naa.

Oriade naa ni Ogoga ko le de ade wa siwaju Olukere amọ o le de fila to wa lori rẹ.

O ni lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ti da ilu Ikere silẹ ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Igoniga se ọdẹ wa lati ilu Agaba, to wa laarin Ijare si Akure.

O fikun pe Ogoga to se ọdẹ wa sinu ilu naa lo ya fila Olukere, eyi to n de sori.

Abọrẹ lasan ni Olukere, ko le fi eeyan joye – Ogoga

Nigba ti oun naa n fesi pada fun Olukere, Ogoga tilu Ikere, Ọba Adejinmi Adu salaye fun BBC Yoruba pe Abọrẹ lasan ni Olukere ninu ilu naa.

Ogoga ni Olukere ko ni asẹ rara lati fi ẹnikẹni joye, koda o fikun pe Olukere kii jade sita.

O ni awọn eeyan to kọkọ de silu Ikere ni wọn wa lati ilu Ilapetu lati Ila, Oke Ikere si ni wọn de si.

“Awọn to de sikeji ni Odo Ọja ti Aladeselu ko sodi, ilu Iselu nilu Benin si lo ti wa, orukọ abisọ rẹ si ni Ogoga.

O ni Ogoga jẹ ọmọọba Ewuare ti Benin amọ nigba ti arakunrin rẹ jọba lo ni oun ko le duro si abẹ asẹ ẹnikẹni, to fi kuro ninu ilu pẹlu awọn eeyan rẹ.

Ogoga yii lo ta Erin lọfa ninu igbo, to si n tọ ipasẹ rẹ lọ, titi to fi ri eefin ni ọọkan eyi to fihan pe ilu ni, to si ba Aladeselu nibẹ.

O pari ọrọ rẹ pe inu ile Aladeselu ni Ogoga gbe fun ọdun meje, ti wọn si fi jọba nitori Aladeselu ni Ifa ti sọ tẹlẹ pe ọmọọba kan n bọ, ti yoo wa jọba le wọn lori.

Ẹ jẹ ka fi ọtẹ silẹ, ka fi ara wa se ọkan, a ko fẹ ija – Olukere ati Ogoga

Lẹyin ọpọ itan, awọn oriade mejeeji wa rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ ilu Ikere pe ki wọn fi ara wọn se ọkan.

Wọn ni ki wọn mase maa ba ara wọn ja nitori ọrọ naa ti wa nile ẹjọ.

Awọn oriade naa tun rọ wọn lati fi ọtẹ silẹ, maa wa ilọsiwaju ilu naa lai si rogbodiyan kankan.