Fídíò, “Ká ní wọ́n fún Awolowo láyèè láti tukọ̀ Nàíjíríà ni, nǹkan kò ní rí báyìí”, Duration 6,21

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba se lonii, itan ni yoo da to ba di ọla, o yẹ ka gbe ile aye se rere.

Oloye Obafemi Awolowo jẹ odu, ti kii se aimọ fun awọn oloko ni agbo awọn ọmọwe ati oselu to ti kọja lọ lorilẹede Naijiria.

Awolowo yii si wa laarin awọn akọni ọmọ Naijiria to gbe ina wo oju awọn oyinbo amunisin lati gba ominiria fun Naijiria.

Bakan naa lo ti tukọ ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, to si se gudugudu meje ati ya ya ya mẹfa fun iran Yoruba lasiko rẹ.

Amọ o se ni laanu pe awọn ọdọ iwoyii ti ọjọ ori wọn ko ju ogun si ọgbọn ọdun lọ ko mọ nipa awọn ribiribi ti Awolowo gbe ile aye se tabi iru eeyan to jẹ.

Ọna lati mase jẹ ki isẹ awọn akọni Naijiria bii Awolowo parun lo mu ki wọn se agbekalẹ ere onise yii ti yoo kọ awọn ọdọ iwoyi ni ẹkọ nipa igbe aye Awolowo ati aya rẹ, Hannah Dideolu Awolowo, HID.

BBC Yoruba ba wọn peju si ibudo ti ere onise ati orin pẹlu ijo naa ti waye, eyi ti igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ati aya rẹ Dolapo, tii se ọmọ-ọmọ Awolowo peju si.

Awọn alejo pataki miran to tun wa nibẹ ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu àti ọmọ-ọmọ Awolowo miran, Olusegun, adari ile asoju-soju, Femi Gbajabiamila to fi mọ awọn eekanlu miran.

Eto miran ti won tun gbekale lati fi sami iranti aya Awolowo naa ni ti ifilole iwe nipa Awolowo ti ogbontarigi onkowe kan ko fun iranti akoni naa.

Ogbeni Lagada Abayomi to je gbajugbaja onkowe ati sorosoro to ko iwe naa ba BBC Yoruba soro lori pataki ki awon omo iwoyi mo sii nipa ipa ti akoni eda naa ko ninu itan iselu Naijiria.

Bee bi omo ko ba ba itan, o di dandan ko ba aroba to je baba itan.