Fídíò ìbálòpọ̀ tó lu jáde nípa olórin Tiwa Savage, èsì ọlọ́rọ̀ gangan rèé

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage

Gbajugbaja akọrin takasufe, Tiwa Savage, ni ẹnu tun ti n kun lori ayelujara bayii,lẹyin ọrọ to sọ fun awọn to n halẹ mọ nitori fidio ibalopọ kan.

Lati ọsẹ to kọja ni ẹnu ti n kún Savage lẹyin to sọ pe fidio to safihan ibi ti oun ti n ni ibalopọ pẹlu ọrẹkunrin oun ṣe e ṣi bọ si ori ayelujara. Eyi ti awọn kan fi n halẹ mọ pe awọn yoo fihan gbogbo eniyan.

Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara rẹ, Tiwa Savage sọ pe awọn to wa nidii ọrọ fidio naa korira oun nitori pe oun fi ọrọ naa ṣe awada lori ìtàgé.

Ọsẹ to kọja ni Tiwa Savage sọ lasiko ifọrọwanilẹnu kan lori eto The Angie Martinez lori redio Power 105.5fm nilu New York, pe awọn eeyan kan ń halẹ mọ oun nitori fidio ibalopọ kan. O ni sugbọn oun ti pinnu lati máa fun wọn ni owo kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tiwa Savage sọ pe oun ti ba eero wọn jẹ pẹlu bi oun ṣe sọ ọrọ naa ni gbangba.

Sugbọn o da bíi pe igbesẹ Savage bi awọn to n halẹ mọ ninu, nitori pe alẹ ọjọ Aje ọsẹ to kọja ni wọn fi fidio ibalopọ kan si ori ayelujara. Àmọ́, ko ti i daju boya Tiwa Savage lo wa ninu fidio naa tabi bẹẹ kọ.

Tiwa sọ pe ẹnikẹni ko le ri fidio naa.

Ọrọ fidio ibalopọ yii si ni ọpọ ọmọ Naijiria n sọ bayi, paapaa lori ayelujara.