Fídíò, Hijab kò dí mi lọ́wọ́ láti di obìnrin agbábọ́ọ́lù láì náání yẹ̀yẹ́ – Zulfah Abdulazzez, Duration 3,47

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamu-ṣamu.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọdọbinrin Zulfah Abdulazzes to si n lo iboju tawọn ẹlẹsin musulumi tawọn mọ si Hijab.

Amọ eyi mu ki Zulfah da yatọ lori papa gẹgẹ niwọn igba to jẹ pe isẹ bọọlu gbigba fawọn obinrin lo yan laayo.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọmọdebinrin naa ni ọmọ ọdun kan ati aabọ ni oun ti n gbe lọdọ iya oun agba, ki onitọun to jade laye lọdun 2017.

Akẹkọọbinrin agbabọọlu naa ni igbe aye le diẹ fun oun amọ afojusun oun ni pe lọjọ iwaju, ki oun di obinrin agbabọọlu to pegede julọ bii Azzezat Oshoala.

Amọ ti ko ba si lori papa lati gba bọọlu, obi, orogbo ati suti ni Zulfah maa n ta labẹ afara Ojota, ko le ri ọwọ mu lọ si ẹnu.