Èyíi tí ẹ ṣe pẹ̀lú òkú Mohbad tó, ẹ yọ̀nda rẹ̀ ká lọ sin-ín — Bella Shmurda, Tonto Dikeh sọ fún Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Aworan Mohbad, Tonto Dikeh ati Belle Shmurda

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad/tontolet/bella_shmurda

Gbajugbaja olorin taka-sufe, Bella Shmurda, ti fajuro si idaduro esi ayẹwo oku Mohbad latọwọ ajọ ọlọpaa.

Shmurda to jẹ ọrẹminu Mohbad lo wi pe o ti le loṣu meji bayi ti ọrẹ oun ti ku amọ ti ko ti pada wọ kaa ilẹ sun lẹyin ti wọn wu oku rẹ lati ṣe ayẹwo ohun to paa.

Lori ikanni X lọjọ Abamẹta ni Shmurda to rawọ ẹbẹ sajọ ọlọpaa lati jọwọ ara oloogbe naa ki wọn lee ṣe ẹyẹ ikẹyin fun-un.

Ninu ọrọ to kọ lori ikanni ayelujara naa ni Shmurda ti wi pe “O ti le loṣu meji bayi ti Moh ku ti ẹ si ti ni ẹ fẹẹ ṣe ayẹwo ohun to paa amọ ti a ko tii ri nkankan ṣugbọn ko buru.

Amọ ẹ jọwọ ẹ yọnda ara rẹ fun wa. Ọdọmọkunrin naa nilo ẹyẹ ikẹyin ko le lọ sinmi.

Ajọ ọlọpaa Naijiria, ki lo n ṣẹlẹ ni pato? A fẹ idahun. Esi ayẹwo tẹẹ ṣe da? Ara oloogbe naa da?”

Tonto Dikeh naa pariwo sita lori bi Ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe kuna lati kede esi ayẹwo oku Mohbad

Aworan Tonto Dikeh

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tontolet

Ilumọọka oṣere sinima lede Gẹẹsi ati Igbo, Tonto Dikeh naa lo ti beere fun ara oloogbe ọhun.

Dikeh naa bere ibeere yii lori ikanni Instagram, to si bu ẹnu atẹ lu bi ajọ ọlọpaa ṣe n fi iwadi lori iku naa falẹ.

Oṣerebirin naa wi pe “Ẹ fun wa ni Mohbad ka lọ sinku rẹ. Iwa aibikita ati ifinkanfalẹ yin ti sun wa. Bi awọn eyan ba dakẹ, emi yoo sọrọ.

Mo ti ṣe ọpọlọpọ wahala lari ri pe idajọ ododo waye lori ọró yii. Gẹgẹ bi QM ṣe wi pe ka fun awọn ọlọpaa laaye diẹ si.

Ni tootọ, a ti fun yin laaye kọja bo ṣe yẹ lọ. Eleyi kii ṣe ọrọ ti wọn lee daṣọ bo. Idajọ ododo la fẹ.”

Isọrọjade awọn mejeeji yii lo n waye lẹyin ti iroyin gbee pe awọn ọlọpaa ti jọwọ olorin to jẹ ọga Mohbad nigba kan ri, Naira Marley, ati Sam Larry ti wọn mu lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku Mohbad.