Ẹ̀rí tuntun jáde nípa nǹkan tó ṣeéṣe kó pa Mohbad

Awọn to sẹ iwọde nigba ti Mohbad ku

Ileeṣẹ eto ilera kan nilẹ America, National Medical Services, NMS, ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti tẹwọgba ohun ti wọn nilo fun ayẹwo lati ṣe iwadii lori ohun to ṣokunfa iku gbajugbaju olorin takasufe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad.

Mohbad, ẹni to jade laye ni ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

NMS fidi iroyin naa mulẹ fun BBC lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa ọdun 2024, ninu atẹjiṣẹ imeeli pe ọkan lara awọn yara ayẹwo ajọ naa ti tẹwọgba awọn ohun ti wọn nilo fun ayẹwo.

Tẹ o ba gbagbe, lati igba ti wọn ti hu oku Mohbad jade lẹyin ti wọn sin, ti wọn si gbe lọ si ile iwosan ijọba ipinl Eko ni iwadii ohun to pa akọrin naa ti bẹrẹ.

Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni ni wọn hu oku Mohbad jade lati lọ ṣe ayẹwo ohun to ṣekupa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin kede loju opo ayelujare pe awọn ti hu oku oloogbe naa.

Ninu oṣu Karun un, ọdun 2024, ni iroyin mii tun bẹ sita pe ajọ NMS kede sita pe awọn ko mọ ohunkohun nipa ayẹwo nipa ohun to ṣekupa Mohbad.

Sugbọn bayii, wọn ti fidi rẹ mulẹ pe awọn eroja ti wọn nilo lati fi ṣe ayẹwo naa ti tẹ wọn lọwọ.

“Gẹgẹ bii wọn ṣe sọ ayẹwo yii yoo fun wọn ni anfaani lati mọ ohun pato to ṣekupa Mohbad.

Ajọ NMS ti wa lati bi aadọta ọdun, ti wọn si ni ẹka kaakiri orilẹede Amẹrika.

Ṣe loootọ ni pe NMS ti pari ayẹwo lori ohun to ṣokunfa iku Mohbad?

Ajọ yii ni otitọ nipe iroyin jade sita ninu oṣu Karun un pe awọn ko tẹwọgba ohun ayẹwo kankan lori iku Mohbad.

“O ṣeni laanu pe, ninu oṣu Karun un ọdun 2024, ọkan lara awọn oṣisẹ wa fi atẹjisẹ sita pe a ko tẹwọgba ohun ayẹwo kankan lori iku Mohbad.

“Ẹkan to n ṣe iwadii DNA ati awọn ami ara mii, to jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko bẹ wa lọwẹ ka ṣe, ti agbẹjọro agba nipinlẹ Eko si buwọlu.”

NMS ni atẹjisẹ ti wọn fi sọwọ si ajọ naa ni o wa pẹlu awọn ohun ayẹwo.

Ajọ naa ni awọn ti pari ayẹwo lori iku Mohbad, ti awọn si ti fi esi ayẹwo naa ransẹ lati inu oṣu Kẹrin ọdun 2024.

Ṣaaju ni Sunday Shoyemi, ẹni to jẹ onimọ nipa ẹya ara ni ileewosan ikọṣẹ isẹgun LASUTH, farahan niwaju ile ẹjọ kan nilu Ikorodu, nibi to ti sọrọ lori esi ayẹwo oku Mohbad.

Iroyin ti kọkọ jade pe Ọgbẹni Shoyemi sọ pe ayẹwo ti wọn ṣe ko ṣafihan nnkan to ṣekupa Mohbad, nitori pe ara rẹ ti n jẹra ko to di pe ayẹwo naa waye.

Ṣugbọn nigba to ba BBC sọrọ, agbẹjọro fun ẹbi Mohbad, Wahab Shittu, ṣalaye nnkan ti ẹni to ṣe ayẹwo oku naa sọ.

O ni “nnkan to sọ ni pe awọn ko mọ nnkan to pa a , to si ti yẹ ki wọn o wu oku rẹ jade laarin wakati mejila fun ayẹwo, ko to di pe o jẹra.

Agbẹjọro naa fikun pe onimọ sayẹnsi naa tka si oogun kan ti oloogbe Mohbad lo ṣaaju iku rẹ, amọ ko le sọ boya oogun naa lo fa iku rẹ tabi bẹẹkọ.

Bakan naa lo sọ pe oun ko tii ri gbogbo akọsilẹ nipa esi ayẹwo oku naa, ti iwadii ṣi n tẹsiwaju