Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀

Pasitọ Elijah Abina ati ọmọ rẹ Emmanuel

Oríṣun àwòrán, Instagram/gofamint

Pasitọ Elijah Abina, to jẹ adari ijọ Gospel Faith Mission International, GOFAMINT, ti padanu ọmọ rẹ ọkunrin, Emmanuel Folorunso.

Iroyin iku ọmọ Pasitọ Abina jade lẹyin ọjọ diẹ ti ọmọkunrin Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye naa jade laye.

Iroyin sọ pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ni Emmanuel Abina ku nilu Eko.

Eyi to jẹ ọjọ kẹjọ ṣaaju iku ọmọ Adeboye.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ pato nkan to pa Emmanuel, iroyin sọ pe aisan ọlọjọ diẹ lo pa a.

Ṣaaju iku rẹ, oun ni pasitọ ẹka ijọ GOFAMINT, Kingdom House Assembly to wa ni Festac Town nilu Eko.

Bakan naa lo tun jẹ oludari ẹka igbohunsafẹfẹ ijọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu atẹjade kan ti Akọwe Agba fun ijọ GOFAMINT , Pasitọ S.O Omowumi fi sita ni ọjọ keji, oṣu Karun-un, lo ti kọkọ kede iku naa.

O ni “pẹlu ẹdun ọkan, ṣugbọn ni itẹriba fun aṣẹ Ọlọrun Olodumare, ni a kede iku arakunrin wa, pasitọ wa, ati ọkan lara ọmọ igbimọ oludari ijọ…

Pasitọ Emmanuel Abina, to ku l’Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

O ni awọn yin Ọlọrun, fun igbeaye oloogbe ati ipa to ni ninu ijọ, paapaa laarin awọn ọdọ.

“Ki Jesu Kristi, Oluwa wa, ko tu Oludari wa, idile, ati ẹbi, to fi mọ ijọ ninu.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ