Ẹ̀kún omi pa èèyàn mẹ́wàá, sọ ọ̀pọ̀ di asùnta lẹ́yìn òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ọjọ́ mẹ́ta

Ẹkun omi

Isẹlẹ ẹkun omi to n waye ni orilẹede Kenya ti gba ẹmi, to si ti sọ ọpọ eeyan di alainilelori mọ.

Awọn oṣiṣẹ meji ni ileeṣẹ to n gba owo ori lorilẹ-ede Kenya ti ẹkun omi gbe lọ ninu ọkọ ni ọjọ Ẹti, ni wọn ti ri ara wọn ni ọjọ Aiku.

Ajọ to n ṣe awari awọn eeyan yii lo tun ri oku ọkunrin kan ti iṣẹlẹ omiyale naa gbe lọ lori alupupu rẹ.

Ọjọ Abamẹta ni awọn alaṣẹ fi lede pe awọn mẹwa ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ omiyale to waye lawọn ilu etido lorilẹ-ede naa lẹyin arọọda ojo ọlọjọ mẹta.

Aworan awọn ero ninu agbara ojo ni Kenya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Kọmiṣọna fun ileesẹ ọlọpaa ni agbegbe Coast, Rhoda Onyancha, fi lede pe o le ni idile ẹgbẹrun lọna ogun to ti padanu ile wọn lawọn ilu mẹta ti wọn faraba ninu iṣẹlẹ naa to fi mọ Mombasa, kilifi, Kwale ati odo Tana.

Ọpọ awọn eeyan lo ti padanu ẹmi wọn ti ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan si ti di alainilelori jakejado orilẹ-ede naa lati ibẹrẹ oṣu kẹsan ti ọwaara ojo ati ẹkun omi ti bẹrẹ si nii ṣọṣẹ nibẹ.

Ọwaara ojo ati ẹkun omi yii lo si ti pa ọpọ ero lawọn orilẹ-ede amuleti kenya bii Somalia ati Ethiopia.

Aworan awọn ero ninu agbara ojo ni Kenya

Oríṣun àwòrán, AFP