Eid al-Adha: Ìdí tí àṣà fífi ẹran ọ̀sìn ṣe ìrúbọ fi wà nínú ẹ̀sìn

Aworan okunrin kan to n fa ewurẹ lọ fun pipa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pọpọṣinṣin ọdun awọn musulumi Eid Al-Adha tabi ọdun irubọ lo bẹrẹ ni ọjọ Abamẹta, ti wọn fi n saamin bi anọbi Ibrahim ti ṣetan lati fi ọmọ rẹ ọkunrin ṣe irubọ.

Ibrahim ni wọn mọ si Abraham ninu ẹsin awọn Juu ati Kristẹni.

Igbagbọ awọn eeyan ni wi pe, Anọbi Ibrahim lo gbọ asẹ latẹnu Allah lati fi ọmọ okunrin rẹ Ishaq rubọ fun oun loju ala rẹ, leyi to si fẹ ṣe ni igbọran si aṣẹ naa.

Nigba to sọ fun ọmọ rẹ, o gba a nimọran lati gbọran si aṣẹ naa, ṣugbọn bo ti n mu ọmọ naa de ibi to ti fẹ paa, ni Allah da a duro to si fi ẹran agbo rọpo fun lati ṣe irubọ.

Awọn ẹlẹsin Islam kaakiri agbaye ni wọn saba maa n pa oriṣiriṣi ẹran ọsin lati fi ṣe irubọ, ni iwọn bi agbara wọn ba ṣe ka a si.

Oju wo ni wọn fi wo ẹran pipa fun irubọ ninu awọn ẹsin miran bii Hindu, Juu ati Kristẹni?

Ẹsin Juu

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ 'Beit Yisrael' ni ẹya Afrika Hebrew Israelite Nation of Jerusalem, march before they slaughter a lamb during a Passover sacrifice ceremony on 12 April 2017

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọsilẹ itan nipa ẹsin Islam lo fẹ farapẹ ti ẹsin awọn Juu ati Kristẹni.

Gẹgẹbi Gary Somers to jẹ olori ẹka ikẹẹkọ ni ile ẹkọ Leo Baeck to wa ni ilu UK ti wi, o ni iwe mimọ ti awọn Juu lo ṣe alakalẹ ọkan o jọkan ilana irubọ wọn ati awọn ibi ti wọn ti n ṣe e.

O ni, ṣugbọn lode oni ko fi bẹẹ si irubọ mọ tori awọn pẹpẹ ti wọn ti maa n ṣe e ni ko si mọ, ati pe ninu adura ni wọn ti n ṣe iranti irubọ naa.

Gary tọka si pe, bi wọn ṣe ba pẹpẹ adura ti awọn ara Romu jẹ ni ko fi si anfaani ṣiṣe irubọ pẹlu ẹran mọ ni Juu, bẹẹ ni ọpọ gbagbọ pe o ti fopin si igbesẹ naa patapata.

O salaye siwaju sii pe, pẹpẹ ti wọn kọ mọṣalaṣi Al-Aqsa si lọwọ ni ilu atijọ Jerusalemu.

Nidi eyi ni awọn Juu fi n gbadura fun atunkọ pẹpẹ naa ki wọn lee pada si asa fifi ẹran ọsin ṣe irubọ gẹgẹbi wọn ti n ṣ ee ni igba iwaṣẹ.

Aworan awọn ara Samaria to duro ti apoti agbọ ẹran agutan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pupọ ninu awọn ẹya Juu ni kii ṣe irubọ lilo ẹranko mọ tori aisi pẹpẹ, ṣugbon awọn ilu mii lara wọn bi i Samaria ni wọn ṣi n ṣe bẹẹ lasiko irekọja, bẹẹ ni awọn kan si maa n fi iye owo ti ẹran mnaa ba ka ṣe itọrẹ aanu.

Ẹran agbo, ewurẹ tabi maalu ni awọn ẹranko to jẹ itẹwọgba fun irubọ ni ilana ẹsin wọn, Gẹgẹ bi ohun ti Dr. Artson ṣalaye, o ni iru awọn ẹranko naa ni wọn maa n pa tabi ki wọn sun un lori pẹpẹ.

Ninu rẹ ni wọn yoo ti fi ranṣẹ si ẹbi Alufaa, bẹẹ ni awọn oni nnkan ati ẹbi wọn yoo si jẹ iyooku rẹ lati lee fidi itan mulẹ.

Dr. Artson tọka sii pe, ẹran jijẹ jẹ ipa kan gboogi ninu ọpọ ọdun ti awọn eeyan maa n ṣe, ṣugbọn ti irubọ ẹran si jẹ ẹbọ ṣiṣe ni ẹya Juu.

Rabbi Gary Somers to jẹ olori ẹka ikẹkọọ nile ẹkọ Leo Baeck to wa ni ilu UK ti salaye, o ni lasiko ọdun tuntun ti awọn Juu ni wọn ti maa fi ẹranko ṣe irubọ.

Ninu iwe mimọ awọn Juu ni itan bi Abraham ti ṣe irubọ ti jẹyọ. Ẹwẹ ilana ọhun lo fẹ yatọ diẹ si ti awọn Juu yooku.

Ẹsin kristẹni

Aworan Jesu kristi ti wọn kan mọ igi agbelebu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati ẹya Juda ni esin kristieni ti ṣẹ wa, bẹẹ akọsilẹ iwe mimọ ti Juu farapẹ akọsile ti iwe majẹmu lailai ninu Bibeli.

Ninu majẹmu lailai, paapa julọ iwe Lẹfitiku ori keje ati Deutaronomi, ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa bi wọn ti n ṣe amulo ẹranko lati fi ṣe irubọ, eyi ti wọn saba maa n ṣe ni owurọ tabi irọlẹ lasiko ti wọn ba ti n ṣe ọdun.

Gẹgẹbi Dr. Proshanto T Rebeiro, tii ṣe alufaa ijọ aguda Kafrul to wa ni ilu Dhaka ti salaye, o ni igbesẹ lilo ẹranko fun irubọ lowa fun iwẹnumọ gbogbo ẹṣẹ ati aiṣedeede nigba naa.

Alufaa na tọka si wi pe, won ko ṣamulo ilana ọun ninu ẹsin kristeni mọ lode oni nitori, bi won ti fi Jesu Kristi ṣe arọpo leyi ti wọn mọ si ọdọ agutan ninu ẹsin igbagbọ.

Aworan ọdọ Agutan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbesẹ fifi ẹran ọsin ṣe irubọ ni ko si ninu alakalẹ ẹsin Kristẹni,ni ọpọ igba lo jẹ wipe ti eeyan ba jẹ ẹjẹ tabi ṣe ileri niwọn maa fifun Ọlorun, ọna ọtọ ni irubọ pẹlu ẹranko jẹ.

Dr. Reberio sọ pe, yatọ fun afarapẹ ti ẹsin awọn Juu ni pẹlu rẹ, wipe ko si ilana ibilẹ kan ko fidi aṣa ẹran pipa mulẹ ninu ẹsin kristẹni rara.

O tẹsiwaju ṣalaye wi pe ko si ofin kan to de aṣa ẹran jijẹ ni ọpọ awọn orilẹ ede, bakan naa losi jẹ ofin ni labẹ ẹsin awọn Juu lati jẹ ẹran ọdọ agutan lasiko ọdun irekọja wọn.

Dr. Reberio ni, lasiko ti oun gbe ni ilu Italy wọn maa n kan an nipa fun gbogbo eeyan lati jẹ ẹran ọdọ agutan saaju ọdun Ajinde.

Ẹsin Hindu

Aworan olori awo to n jo pẹlu ẹran ewure ti wọn fẹ pa fun irubọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkan o jọkan awuye wuye lo wa lori ọrọ fifi ẹran ọsin ṣe irubọ ninu ilana ẹsin Hindu, bẹẹ ni awọn ẹya Hindu kọọkan ṣi n ṣe e.

Dr. Kushal Baran Chakraborty to jẹ igbakeji ni ẹka ikẹkọ kan ni Unifasiti ilu Bangladesh sọ pe, ninu iwe mimọ atijọ ti ẹsin Hindu ni wọn ti ṣakọsilẹ aṣa ẹran pipa fun irubọ.

Fun apẹẹrẹ ọpọ awọn eeyan ni ilu India ati Bangladesh ni wọn ti maa fi ẹran ṣe irubọ Lasiko ọdun wọn.

O mẹnuba bi igbẹsẹ naa ti maa n ṣiṣẹ itusile latinu igbekun fun awọn eeyan ibẹ, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ẹsin Hindu.

Irufẹ awọn ẹran ni wọn fi n rubọ si orisa, ti awọn eeyan yoo si jẹ iyooku rẹ nibi ayẹyẹ wọn, bo ti lẹ jẹ wipe igbesẹ ẹran pipa fun irubọ lo ṣi n fa aigbọra ẹniye laarin awọn ọmọran ode oni ni ilẹ India.

Dr. Kushal Baran Chakraborty tọka sii pe lawọn pẹpẹ atijọ bii Dhakeshwari ni Bangladesh, Tripura Sundari, Kamakhya oun Kalighat Kali nilu India ni aṣa naa ti saba maa n waye.

Ẹwẹ, Dr. Rohini Dharmapal to jẹ oguna gbongbo ninu ẹsin Hindu sọ pe oun ko mọ si bi ọrọ fifi ẹran ọsin ṣe irubọ ti gbale gboko ni ilu India ode oni.

Dr. Chakraborty fikun ọrọ rẹ pe, pupọ ninu awọn to n ṣe irubọ ẹran naa ninu ẹsin Hindu naa laye ode oni, ni wọn n ṣe e fun ifẹ inu ara wọn tabi fun ifigagbaga leyi to tabuku iṣemimọ ilana irubọ naa.

Oriṣiriṣi ẹgbẹ ni ilẹ India ni wọn ti finu findọ jawọ ninu igbesẹ naa nibi pẹpẹ wọn, bẹẹ ni wọn si pe fun fifagile aṣa ẹran pipa fun irubọ nitori ọrọ ẹsin nibẹ.

Orilẹ ede Sri Lanka ati Nepal ti fofinde igbesẹ ẹran pipa fun irubọ latọwọ awọn ẹlẹsin Hindu, ṣugbọn to jẹ wi pe wọn kii fi gbogbo igba tẹle ofin naa.