Ẹgbẹ́ wa ló gbé Tani Ọlọhun’ ṣùgbọ́n ìjọba ló gbé e wá sí Ilorin, Ẹgbẹ́ tó ń bá Tani Ọlọhun ṣẹjọ́ ní Ilorin ṣàlàyé

Ẹgbẹ́ wa ló gbé Tani Ọlọhun’ ṣùgbọ́n ìjọba ló gbé e wá sí Ilorin, Ẹgbẹ́ tó ń bá Tani Ọlọhun ṣẹjọ́ ní Ilorin ṣàlàyé

Aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ ilu Ilorin, Muritadoh AbdulKareem ti ọpọ mọ so BabanBariga ti sọ pe ẹsin Islam ni aṣa gbogbo ọmọ ilu Ilorin, ajoji si ni iṣẹṣe jẹ nibẹ.

Babanbariga lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lasiko to n sọrọ lori eredi ti awọn Alfa ṣe gbe gbajumọ Musulumi kan to pada di oniṣẹṣe lati ilu Ibadan lọ si Ilorin lori ẹsun ibanilorukọjẹ, Tani Olohun.

O ni ojulowo ọmọ ilu Ilorin kii bọ oke, omi tabi nnkan mii yatọ si Islam.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ọpọ ọmọlẹyin Kristi ati awọn oniṣegun kun inu ilu naa, awọn oniṣẹsẹ nikan lawọn fọwọ si.

“Iṣẹ ni iṣegun, iṣẹ yatọ si aṣa…o yatọ si ẹsin, ko si ọmọ Ilori kan to n ṣe iṣẹṣe.”

“Ọpọ ṣọọṣi lo wa niluu Ilorin, awọn oniṣegun naa wa, amọ ki ẹ wa duro pe o daa o, a fẹ maa bọ oke o, a fẹ maa bọ odo, aṣa ni, kii ṣe aṣa ilu Ilorin, ẹni to ba fẹ ṣe iyẹn ko lọ ibomii.”

Ẹsun ti wọn fi kan Tani Olohun

Lori eredi ti wọn ṣe gbe Tani Olohun, AbdulKareem sọ pe ẹsun ibanilorukọjẹ ati ipurọmọni ni awọn fi kan an.

O ṣalaye pe Tani Olohun pa irọ mọ awọn olori ilu Ilorin, o si tun ba wọn lorukọjẹ lo jẹ ki awọn lọ fi ẹjọ rẹ sun ijọba.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe awọn ko fi Emir wọn atawọn adari wọn mii ṣere ṣugbọn Tani Olohun n fi abuku kan awọn eeyan naa ti awọn n bu ọla fun.

Ẹgbẹ wa lo gbe Tani Olohun, amọ ijọba lo gbe wa si Ilorin

BabanBariga ṣalaye pe ẹgbẹ Ogo Ilorin lo fi ofin gbe Tabi Olohun bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa lo gbe lọ siluu Ilorin.

Gẹgẹ bii alaye to ṣe, o ni awọn lo lọ fi ẹjọ afurasi naa sun ijọba ki ijọba to gbe igbesẹ lati mu un.

“Ijọba la fi ẹjọ sun, ijọba lo si fi ọwọ ofin gbe.”

“Bawo ni eeyan ṣe le lọ gbe eeyan lati ilu kan si omiran ki ijọba ma mọ si?

“Ijọba lo lọ gbe niluu Ibadan nitori pe ilu Ibadan lo n gbe.”

“Igba ti a lọ fẹjọ rẹ sun la gbọ pe o ti de, ko si ẹnikan nibẹ ju ijọba lọ.”

Amọ ṣa, ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti sọ pe oun ko lọwọ ninu bi awọn Alfa naa ṣe fi panpẹ ofin gbe afurasi ọhun.

Ajayi Okasanmi to jẹ alukoro ilẹeṣẹ ọlọpaa Kwara lo sọ bẹẹ fun BBC.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti BabanBariga sọ.