Ẹgbẹ̀ òṣèlú PDP wọ́ Tinubu lọ sílè ẹjọ́, rọ ilé-ẹjọ́ láti wọ́gilé tíkẹ́ẹ̀tì rẹ̀

Tinubu

Oríṣun àwòrán, BolaTinubu/facebook

Igbimọ ipolongo aarẹ fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ nilana ofin lati yọ oludije sipo aarẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), Bola Tinubu, lati maṣe dije dupo aarẹ ọdun yii.

Agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo PDP, Kola Ologbodiyan, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Abuja sọ pe ẹgbẹ PDP gba ile-ẹjọ lati beere ki ile-ẹjọ da Tinubu duro lati dije nitori awọn ẹsun ti o ni ṣe pẹlu gbigbe ogun oloro ni orilẹ-ede Amẹrika to wa lọrun rẹ. 

Ẹgbẹ oṣelu PDP beere lọwọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun ajọ eleto idibo ti orilẹ-ede yii (INEC) lati tete yọ Bola Tinubu  gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ APC tabi eyikeyii ẹgbẹ oṣelu.

 Ẹgbẹ naa pe fun eto idajọ kiakia lori awọn ẹsun ti wọn fi kan Bola Tinubu ti wọn si pe fun idajọ to peye lori ilana ofin to dena awọn ti wọn ti wu iwa ọdaran lati dije dupo oṣelu orilẹ-ede yii.

Ṣaaju akoko yii ẹgbẹ oṣelu PDP ti kuna ni ile ẹjọ lati fofin de Bola Tinubu ẹsun eyi ti ile ẹjọ da sita.

 Ni ọjọ kẹtala Oṣu Kiini, ọdun 2023 ni ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ ni Abuja wọgile ẹjọ kan ti ẹgbẹ PDP pe ki wọn yọ Tinubu ati igb keji rẹ, Kashim Shettima kuro ninu idibo aarẹ ọdun yii.

Nigba ti o n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Inyang Ekwo da ẹjọ naa silẹ nitori pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko ni ẹri to daju  lati gbe ẹjọ naa lẹsẹ.

Adajọ Ekwo ṣapejuwe ẹjọ naa gẹgẹ bi ilokulo ilana ile-ẹjọ.