Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Cameroon àti Comoros

Papa isere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko din ni eeyan mẹjọ to kú, lasiko wọ́lù-kọlù to waye ni papa isere Olembe ti idije Afcon ti n waye ni Cameroon lọjọ Aje.

Ọpọ eeyan lo tun farapa.

Fidio kan safihan bi àwọn ololufẹ bọọlu ṣe n tiraka lati wọ papa isere ọhun to wa ni olu ilu Cameroon, Yaoundé.

Gomina ẹkùn aarin gbungbun Cameroon, Naseri Paul Biya sọ fun ileeṣẹ iroyin AP News pe, o ṣe e ṣe ki oku pọ si i.

Iroyin miran tun sọ pe awọn ọmọde kan dákú nitori wọ́lù-kọlù naa.

Bawo ni isẹlẹ naa se waye:

Iwadii BBC salaye pe ẹgbẹrun lọna ọgọta eeyan ni papa isere naa le gba, sugbọn wọn din ku si ìdá ọgọrin nitori COVID-19.

Ṣugbọn àwọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ to ba oniroyin sọ̀rọ̀, sọ pe eeyan bi ẹgbẹrun lọna aadọta lo n gbiyanju lati wọle sibi ifẹsẹwọnsẹ laarin

Ileeṣẹ iroyin orile-ede Cameroon, sọ pe eeyan mejila lo ku, ti ogunlọgọ si ku.

Igbesẹ wo ni ajọ elere bọọlu ni Afirika gbe?

Àjọ bọọlu ni Afrika, CAF, sọ ninu atẹjade pe awọn ti n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni CAF sọ pe Ààrẹ àjọ naa, Ọmọwe Patrice Motsepe ti ran Akọwe Agba, Veron Mosengo-Omba, lọ si ileewosan lati lọ ṣe ibẹwo si awọn to farapa.

Nick Cavell, olootu eto fun BBC Africa, to wa nibi ifẹsẹwọnsẹ ọhun sọ pe iroyin wọ́lù-kọlù naa ko de eti awọn to ti wa ninu papa naa, titi di asiko ti iroyin naa jade si ori ayelujara.

Cavell sọ pe ni ṣe ni bata ati awọn nkan miran kún ẹnu ọna papa isere.

Olutọju alaisan kan, Olinga Prudence sọ fun ileeṣẹ iroyin AP pe, awọn kan wa ni bebe ikú lara awọn to farapa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kí ló ti ṣẹlẹ sẹyin:

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọjọ́ kan pere ti eeyan mẹrindinlogun kú nile igbafẹ LIVS Night club ni agbegbe Bastos nilu Yaoundé.

Botilẹ jẹ pe wọ́lù-kọlù waye, ko da ifẹsẹwọnsẹ to n lọ laarin Cameroon ati Comoros duro.

Ami ayo meji si odo ni Cameroon fun Comoros.