“Èèyàn 34 ló kú nínú ẹbí mi nígbà tí àdó olóró ọmọ ogun Naijria balẹ̀ sí abúlé wa”

Kaduna bom blast

Oríṣun àwòrán, getty images

Ọkunrin ọmọ ipinlẹ Kaduna kan ti ṣalaye pe eeyan mẹrinlelọgbọn lo jade laye ninu ẹbi oun nikan ṣoṣo lẹyin ti ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria sọ ado oloro si abule wọn nipinlẹ Kaduna.

Ọkunrin ọhun to pe orukọ ara rẹ ni Idris lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC.

Idris ṣalaye pe “O kere tan, a maa n ṣe ọdun Maulud nigba mẹẹdogun lọdọdun, ọkọ ofurufu naa sọ ado oloro si gbagede ti a ti n ṣe ọdun ọhun, nibi to ti pa awọn eeyan wa, pẹlu obirin atawọn ọmọde.”

“Ni ṣe ni ẹya ara awọn kan lara awọn to ku pin yẹlẹyẹlẹ, ado oloro keji balẹ le awa ti a n lọ ko oku awọn to jade laye.

“Nnkan bii eeyan mẹrinlelọgbọn ni a pada ninu ẹbi wa nigba ti eeyan mẹrindinlaadọrin mii farapa.”

Lẹyin naa lo ke si ijọba ko san owo gba mabinu fun awọn ẹbi awọn to jade laye.

“Mo ri ẹya ara eeyan to fọn kaakiri”

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, A’isha sọ fun BBC pe oju oun ni wọn n ko oku awọn eeyan sinu apo.

O ni “Nnkan bii aago mọkanla alẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye; wọn pe mi lori aago amọ ilẹ ti ṣu, aarọ ọjọ keji ni mo to lọ si abule naa.

“Oju mi koro ni wọn ti n ṣa awọn oku, lara awọn oku naa si ti pin yẹlẹyẹlẹ.

“Lara awọn ẹya ara awọn oku naa fọn ka si ẹka igi, nigba ti awọn mii wa lori orule ile.

“Aarin ọgbọn iṣẹju sira ni awọn ado oloro naa balẹ lerelera.

“Awọn to lọ ko oku awọn ti ado oloro akọkọ ṣekupa lo fara kasa ado oloro keji.

“Awọn obinrin kan ku ti ọmọ ṣi wa lọrọ wọn, awọn ọmọ mii ye ikọlu naa nigba ti awọn ọmọ mii ku pẹlu awọn iya wọn.”

Wo ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀tọ̀ tí ọkọ̀ òfúfurú ọmọ ogun Nàìjíríà ti ṣèṣì ju àdó olóró sí aráàlú

Aworan ikọlu ado oloro kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii ni ọkọ ogun oju ofurufu ileeṣẹ omọ ogun Naijiria ju ado oloro si aarin awọn araalu nipinlẹ Kaduna.

Iroyin ni ajọdun Maulud Nabiyy lawọn eeyan naa n ṣe ni ilu Tudun Biriin, to wa nijọba ibilẹ Igabi, ki iṣẹ naa to waye.

Iroyin ni eeyan mẹrindinlaadọrun un (86) lo jade laye latari iṣẹlẹ naa, nigba ti awọn mẹrindinlaadọrin (66) mii farapa yanayana.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọmọ ogun naa ti kọkọ sọ pe oun ko mọ ohunkoun nipa iṣẹlẹ ọhun, amọ lẹyinorẹyin, o pada sọ pe iṣẹ ọwọ oun ni amọ aṣiṣe ni.

Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti ọkọ ogun oju ofurufu ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria yoo ṣeṣi ju ado oloro lati oke si awọn araalu.

Iye igba ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti ṣeṣi ju ado oloro si arin araalu ree:

Oṣu kinni, ọdun 2023

Ko din ni eeyan mẹtadinlaadọta to jade laye lagbege Rukubi, nipinlẹ Nasara, nigba ti ado oloro ileeṣẹ ọmọ ogun balẹ sibẹ.

Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye sunmọ ala ilẹ ipinlẹ Benue ati Nasarawa.

Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ nigba naa pe awọn janduku loun n dojukọ ogun naa kọ, kii ṣe araalu.

Oṣu Keji ọdun 2022

Aworan ikọlu kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu oṣu keji, ọdun 2022 ni ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ṣekupa ọmọde meje, ti ọpọ eeyan mii si farapa lorilẹ-ede Niger.

Iroyin ni awọn janduklu ni ikọlu naa dojukọ amọ awọn araalu ba a lọ.

Oṣu kejila, ọdun 2022

Ninu oṣu Kejila ọdun ni ado oloro ọmọ ogun Naijiria ṣekupa eeyan mẹrinlelọgọta ni ilu Mutumji, ni ijọba ibilẹ Zamfara.

Awọn eeyan to wa nibẹ sọ pe pupọ lara awọn to ku lo jẹ janduku amọ ọpọ araalu naa jade laye ninu ikọlu ọhun.

Lara awọn to ku ni obinrin atawọn ọmọde wa.

Oṣu Kẹfa, ọdun 2022

Aworan iṣẹlẹ ado oloro kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agọ awọn janduku ni awọn ọmọ ogun n doju ija kọ ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ko to ṣẹṣi pa awọn araalu.

Abule Kunkuna, nijọba ibilẹ Safana to wa ni ipinlẹ Katsina ni isṣẹlẹ ọhu ti waye.

Ọpọ eeyan lo jade laye nibẹ.

Ọdun 2021

Ọkọ ofurufu ọmọ ogun kan to n lọ koju ikọ Boko Haram ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ṣeṣi sọ ado oloro si awọn akẹgbẹ rẹ.

Iroyin ni ko din ni ogun ọmọ ogun to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Oṣu Kẹsan an, ọdun 2021

Ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 kan na, ọkọ ofurufu ọmọ ogun Naijiria ju ado oloro si aarin abule kan ni ijọba ibilẹ Yunusari, nipinlẹ Yobe.

Eeyan mẹwaa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Àwa la wà ní ìdí àdó olóró tó ṣ’ọṣẹ́ ní Kaduna – Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà

Aworan Ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti ni ibugbaamu ado oloro to sekupa ọpọ eeyan nibi ajọdun Maulud Nabiyy ni ilu Tudun Biriin nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna ko sẹyin wọn.

Ileeṣẹ ologun ni ibu gbamu lo je asise lasiko ti awọn ọmọ ologun n gbena woju awọn ọdaran ni agbegbe naa.

Ọgbọn eeyan lo ti jade laye lẹyin ibu gbamu naa.

Kọmisana fun eto abo abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan, ninu atẹjade to fi lede ni Ileeṣẹ ologun ti kede pe ọdọ wọn ni ado oloro naa ti wa.

Ninu atẹjade naa lo ti salaye ohun to waye nibi ipade ti ijọba ipinlẹ Kaduna ṣe pẹlu awọn Ọga agba Ileeṣẹ ologun ati awọn olori ẹṣin.

“Ijọba ipinlẹ Kaduna ti gbọ ohun to waye nibi ibugbamu ọjọ Aiku ni bi to ọpọ eeyan ti dero ọrun, ti ọpọ mii si farapa yanayana.

“Ninu ipade ti igbakeji Gomina, Dr Hadiza Sabuwa Balarabe ṣe pẹlu Ọga ileeṣẹ ologun ati awọn olorin ẹṣin ni Ileeṣẹ ologun ti salaye ohun to sokunfa ibugbaamu naa.

“Ọga agba fun Ileeṣẹ ologun One Division, Ọgagun VU Okoro salaye pe ileeṣẹ ologun n lepa awọn ọdaran kan nigba ti wọn ṣeesi ju ado oloro sọdọ awọn araalu ni agbegbe naa.”

Àdó olóró bú gbàmù, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò nibi àjọ̀dùn Maulud Nabiyy

Aworan ibugbaamu oloro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ awọn araalu ni ipinlẹ Kaduna lo ti dero ọrun lẹyin ti ado oloro bu gbamu lasiko ti ayẹyẹ Maulud Nabiyy n lọ lọwọ ni Tudun Biri, agbegbe kan to wa ni ijọba ibilẹ Igabi.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn sọ fun BBC pe ọganjọ oru ni isẹlẹ naa waye nigba ti ọkọ ofurufu ju ado oloro si aarin awọn olujọsin lasiko ayẹyẹ Maulud.

“A n ṣe ayẹyẹ ọjọbi Anọbi Mohammad lọwọ nigba ti ọkọ ofurufu baalu ju ado oloro, to si jẹ pe o to ọgbọn eeyan to jade laye lẹsẹkẹsẹ.”

O ṣeeṣe ki alekun ba iye awọn to gbe ẹmi mi ni bi isẹlẹ ado oloro naa.

Bello Shehu Ugara ni obinrin ati ọmọde wa lara awọn eeyan to jade laye.

Ọpọ lo ti naka si ileeṣẹ ologun ofurufu orilẹede Naijiria NAF pe wọn lọwọ ninu bi ado oloro naa se bugbaamu.

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti fi di isẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si sapejuwe ibugbaamu naa gẹgẹ bi ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ.

‘Ọgbọn eeyan miran wa ni ile iwosan’

Oṣojumikoro tun salaye fun BBC pe o to ọgbọn eeyan ti awọn gbe lọ si ile iwosan ni abule Buruku.

O ni orukọ Ile ijọsin naa ni Madrasatul Madinatul Ahbab wa Talamiz.

O tẹsiwaju pe ọdọdun ni ayẹyẹ Mawludi ni ile ijọsin naa, ti wọn si n tun gbero lati se ayẹyẹ mii lalẹ ọjọ Aje.

Bello Ugara ni “Ati obinrin ati ọmọde lo ba isẹlẹ naa lọ.

“Awọn iyawo ile, awọn obinrin ti ku, ti ọmọ wọn si wa lẹgbẹ wọn tabi ki ọmọ ku.

“Awọn ọdọ naa pẹlu awọn to jade laye, ti wọn jẹ ọkunrin ati obinrin.”

Aworan awọn eeyan to wa ni ile iwosan

Oríṣun àwòrán, KADUNA AIRSTRIKE VICTIMS

A ko mọ nipa ado oloro to bugbaamu ni Kaduna- Ileeṣẹ ologun NAF

Ileeṣẹ ologun ofurufu ilẹ Naijiria, NAF ti fọhun sita lẹyin ti awọn araalu fẹsun kan wọnm pe wọn lọwọ ninu ado oloro to bugbaamu ni ipinlẹ Kaduna.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ NAF. Edward Gabkwet fi lede fun awọn akọroyin salaye pe Ileeṣẹ ologun NAF ko fi igba kankan ju ado oloro si awọn agbegbe nipinlẹ Kaduna.

“Laarin wakati mẹrinlelogun, ako gunle isẹ kankan ni igboro ipinlẹ Kaduna.

“O ṣe koko pe ki gbogbo ilu mọ pe ko ki n ṣe ileeṣẹ ologun NAF nikan lo wa ni apa ariwa orilẹede Naijiria to n lo ado oloro .”

Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹlu bi awọn oniroyin ṣe kọ lati se iwadii wọn daa ki wọn to gbe iroyin sita fun araalu.