Ẹ̀ẹmàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti pààrà ilé ẹjọ́ látìgbà tí mo ti gbégbá ìbò àmọ́… – Rukayat Shittu

Rukayat Shittu

Oríṣun àwòrán, @Rukayatshittu06/X

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Abuja ti dájọ́ pé Rukayat Shittu, olùdíje sílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kwara láti sọjú ẹkùn Owode/Onire lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ló jáwé olúborí níbí ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹta ọdún 2023.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ èyí tí wọ́n fi yí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò padà.

Ṣáájú ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ní ilé ẹjọ́ gíga ní ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara ti ní ìbò tó gbé Rukayat Shittu wọlé kò parí tí wọ́n sì ní kí wọ́n tún ìbò dì ní àwọn ibùdó ìdìbò kan.

Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Abdullahi Yinusa Magaji ló wọ́ Rukayat Shiitu lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò pé Rukayat kọ́ ló wọlé ìdìbò náà.

Adájọ́ Ademola Enikuomehin tó ṣáájú ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 pé kí àtúndì ìbò wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò kan.

Èyí ló mú kí Rukayat pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti fi tako ìdájọ́ náà, tó sì ní kí ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni òun jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Ẹjọ́ tí àwọn adájọ́ Nàìjíríà ń gbọ́ lọ́dún ju ti àpapọ̀ US, UK àti France lọ

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tuntun yìí, Rukayat Shittu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ ní ìdájọ́ yìí ti fòpin sí gbogbo awuyewuye tó ń wáyé lórí ètò ìdìbò tó gbé òun wọlé.

Rukayat Shittu ní láti ìgbà tí òun ti gbégbá orókè gẹ́gẹ́ bí olùdíje ní ẹgbẹ́ APC nínú oṣù Kẹfà ọdún 2022 ni òun ti ń ti ilé ẹjọ́ kan bọ́ sí òmíràn.

Ó ní láti ilé ẹjọ́ gíga ni òun ti bẹ̀rẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn títí tí àwọn fi dé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórí ta ni ojúlówó olùdíje tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ dìbò yàn níbi ètò ìdìbò abẹ́nú.

Ó ní èyí fún òun ní ìrírí láti mọ ìpèníjà tí àwọn adájọ́ Nàìjíríà ń kojú àti pé ẹjọ́ tí wọ́n ń gbọ̀ pọ̀ púpọ̀.

Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa ṣe sùúrù pẹ̀lú ẹ̀ka ètò ìdájọ́ nítorí i’sẹ́ tó wà lọ́rùn wọn pọ̀ ju ohun tí àwọn ènìyàn kàn ń rí ní ìta lọ.

Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ẹkùn rẹ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fun láti ìgbà tí ètò ìdìbò náà ti bẹ̀rẹ̀ títí di àsìkò yìí.

“Àtìlẹyìn tí àwọn ènìyàn Owode/Onire ṣe fún mi kò kéré rárá, tí mi ò sì lè kó iyán wọn kéré rárá ìfarajìn àti pé ipá gómìnà Abdulrasaq lórí ẹjọ́ náà kó kéré rárá.”

Ta ni Rukayat Shittu?

Ọdun 1996 ni wọn bi omidan Rukayat Shittu

O jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn bayii.

O kawe gboye nile ẹkọ National Open University ni Naijiria.

O jẹ ọmọ bibi ilu Manyan ni Owode Onire ni ijoba ibile Asa ni ipinle Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.

Rukayat salaye awọn ohun to gbe e dide ati bi ọpọ sẹ n satileyin fun un nipinle Kwara fun BBC Yoruba.