Ẹbí ‘Tani Ọlọhun’ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Shehu àti àgbàgbà ẹ̀sìn ní Ilorin láti dáríjin èèkàn Oníṣẹ̀ṣe náà

Ọkan ninu awọn mọlẹbi Tani Olohun, Rofiat Adegbola ti rawọ ẹbẹ si awọn Alfa ilu Ilorin ki wọn forijin aburo oun lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Rofiat lo rawọ ẹbẹ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba nile ẹjọ ti igbẹjọ afurasi ọhun ti n lọ lọwọ niluu Ilorin.

Ẹsun ibanilorukọjẹ ati iparọmọni ni awọn Alfa naa, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ “Ogo Ilorin” fi kan Tani Olohun, ki wọn to fi ọwọ ofin gbe.

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, tani olohun

Mọlẹbi rẹ ọhun ni “Mo wa lati wa bẹ gbogbo eeyan, mo bẹ gbogbo ẹyin Alfa Ilorin, mo bẹ gbogbo ẹyin ọlọla ilu Ilorin, mo bẹ baba wa Sehu ọlọla ilu Ilorin.”

“Mo bẹ yin ni orukọ Ọlọrun, mo fi ilẹ Ilorin bẹ yin… ki ẹ ba mi darijin Abdulazeez T.O. ti gbogbo eeyan mọ si Tanbi Olohun ti wọn fi ẹsun kan an pe o n ba wọn Alfa lorukọ jẹ.”

Yatọ si awọn Alfa ti arabinrin naa rawọ ẹbẹ si lorukọ aburo rẹ, o tun bẹ ọba ilu Ilorin naa pe ko jeburẹ.

Obinrin ọhun tun bẹ gbogbo awọn abiyamọ aye ki wọn forijin aburo oun lori ẹṣẹ to ṣe awọn Alfa ilu ọhun.

Yatọ si mọlẹbi Tabi Olohun to n ba bẹbẹ yii, awọn alẹnulọrọ mii lawujọ naa tun ti da si ọrọ naa.

Lara wọn ni arabinrin Yinka TNT ati Adekunle Adelana, ti ọpọ mọ si Ọba Solomoni.

Wayi o, ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn Alfa naa ṣe ku giri gbe afurasi ọhun lati ilu Ibadan lọ siluu Ilorin lati lọ jẹjọ, ninu eyii ti ileeṣe ọlọpaa sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa bi wọn ṣe mu.

Ẹwẹ, Musulumi ni Tani Ohun tẹlẹ ko to pada di oniṣẹṣe to si maa n sọko ọrọ si awọn ẹlẹsin Musulumi to ti n sọrọ kobakungbe si ẹsin Iṣẹṣe ṣaaju.