Ẹ tú Baba Ijesha sílẹ̀ pẹ̀lú Béèlì, ẹ má ṣi agbára òfin lò bí bẹ́ẹ̀ kọ́

Yomi Fabiyi ati Baba Ijesha

Oṣerekunrin, Yọmi Fabiyi tun ti sọ oko ọrọ mii si ori ayelujara lori bi akẹẹgbẹ rẹ, Omiyinka, Baba Ijẹṣa, ṣe wa ni ahamọ ọlọpaa nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Lati igba ti ọwọ ti tẹ Baba Ijẹsha ni Fabiyi ti n sọ oriṣiriṣi ọrọ lati fi sẹ atilẹyin fun un.

Ẹsun fifi ipa ba ọmọde lopọ lọna aitọ ni wọn fi kan oṣerekunrin naa, lati ọwọ apanilẹrin, Princess Comedian.

Ọpọ igba to si ṣe bẹẹ ni awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu u, paapaa lori ayelujara. Koda, ọrọ naa fa titahun sira ẹni laarin oun ati oṣerebinrin, Iyabọ Ojo.

Lọtẹ yii, Yomi Fabiyi sọ pe o tako ofin Naijiria lati maa gba beeli afurasi ọdaran.

Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ ni owurọ ọjọ Satide, eyi to pe akọle rẹ ni “Ẹ tu Baba Ijẹsha silẹ kiakia”, Fabiyi sọ pe o lodi si ofin Naijiria lati fi afurasi kankan si ahamọ ju boṣeyẹ lọ lai gba beeli rẹ tabi gbe lọ si ile ẹjọ.

“Ti ẹ ba ṣi fi si ahamọ, eyi tako ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ọmọniyan, o si jẹ ifiyajẹni ati aṣilo agbara. Ẹ ma ṣe dan-an wo.”

O ni ile ẹjọ nikan lo le fi aṣẹ si fifi afurasi pamọ kọja wakati mejidinlaadọta ti ofin Naijiria la kalẹ.

O ti le ni ọsẹ meji ti Baba Ijẹsha ti wa ni ahamọ ọlọpaa.

Ṣaaju ni Fabiyi ti kede ni ọjọ diẹ sẹyin pe oun yoo ṣeto iwọde ifẹhonuhan fun ọjọ meje, ti ileeṣẹ ọlọpaa ba fi kuna lati tu Baba Ijẹsha silẹ.

To si tun ṣe bi ẹni n ṣe atẹnumọ rẹ ninu ọrọ to kọ ni owurọ Satide pe igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa to ìdí lati ṣe iwọde alaafia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ