Ẹ kọ̀wé fípò sílẹ̀, ti ẹ kò bá le san owó oṣù tuntun – Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sí àwọn Gómìnà

Aworan egbe osise ati egbe awon Gomina lorileede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC tí fẹsun kan ẹgbẹ awọn Gomina lorilẹede Naijiria pe wọn ní erongba buburu si jiroro ọrọ owo oṣu tuntun to n lọ lọwọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ awọn Gomina lorilẹede faake kọri pe awọn ko ni agbara lati san owo oṣu #60,00ọ b fun awọn osisẹ nipinlẹ wọn.

Ninu atẹjade tí Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Halimah Ahmed fi lede fun awọn akọroyin, awọn Gomina ni owo naa pọju agbara wọn lọ, ti ko si le fẹ sẹ mulẹ.

Ẹgbẹ Gomina tun fikun pe tí ìjọba apapọ ati ẹgbẹ osisẹ ba fẹnu ko lori #60,000 gẹgẹ bii owo oṣu tuntun, ọpọ awọn ipinlẹ ni ko ni le san owo naa fun awọn osisẹ wọn.

Ẹwẹ, ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria ni gbogbo ohun ti wọn bẹrẹ fun ni kí ìjọba ṣe lori ọrọ owo oṣu tuntun tí Gomina tí ko ba le san owo oṣu naa kọwe fipo silẹ.

Igbakeji Aare TUC, Tommy Etim ba Ileeṣẹ iroyin The Punch sọrọ;

“Gbogbo nnkan to jọ mọ owo oṣu tuntun ni o gbọdọ wa si imusẹ.

“Fun awọn Gomina, a ti la han wọn, ti wọn ko ba le san owo oṣu tuntun yii, ko kọwe fipo silẹ nitori a dibo fun wọn fun ijoba rere ko se fun ohun alumọni nìkan.

“Ni orilẹede Naijiria ti awọn Gomina tí ń sọpe #30000 pọju lati san gẹgẹ bii owo oṣu ni Gomina kan ni gbe ẹsẹ le #80bn.

“O mase, a ko ni fo igbesẹ kankan. Ẹgbẹ osisẹ yoo se ipade. A n fun Aarẹ ni anfani lati sọrọ.”

Bakan naa ninu atẹjade ẹgbẹ osisẹ Labour, Benson Upah fi lede, o ni awọn gbagbọ pe awọn Gomina lorilẹede Naijiria gbe igbesẹ naa pẹlu erongba buburu.

“Pẹlu nnkan ti wọn sọ, ko si nnkan to le le wa kuro nibi otitọ nitori afikun tí wa fun owo FAAC awọn Gomina lati #700bn sì 1.2trn, eyi to fihan pe owo n bẹ lọwọ awọn Gomina

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria Gov Forum