Ẹyin ọmọ tí wọ́n kó pamọ́ láti 1992 di ìbejì lántì-lanti ní 2022

  • Author, Busayo James-Olufade
  • Role, Broadcast Journalist
Ibeji

Oríṣun àwòrán, NATIONAL EMBRYO DONATION CENTER

Ẹyin obinrin kan ti wọn ko pamọ lati ọgbọn ọdun sẹyin ti di ọmọ to jẹ ibeji.

Iṣẹlẹ naa waye ni ipinlẹ Tennessee ni orilẹ-ede America.

Igbagbọ wa pe ẹyin ọmọ naa ni eyi ti wọn ko pamọ fun igba pipẹ julọ, to si tun pada di ọmọ.

Lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, Ọdun 1992, ni wọn ti ko wọn pamọ sinu eroja nitrogen.

Iya awọn ọmọ tuntun naa, Rachael Ridgeway, to jẹ iya ọlọmọ mẹrin, bi awọn ibeji tuntun naa ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, dun 2022.

Tọkọtaya kan ti wọn ko darukọ wọn, lo ni awọn ẹyin ọmọ naa ti wọn kojọ fun eto IVF, ki wọn le ri ọmọ bi.

Ọjọ ori tọkọtaya ti wọn ko darukọ naa jẹ aadọta ati mẹrinlelọgbọn lasiko ọhun.

Lati ọdun 1992 si ni wọn ti ko wọn pamọ si ibudo ilera kan ni Guusu America titi di ọdun 2007, nigba ti tọkọtaya naa yọnda wọn fun NEDC niluu Knoxville, Tennessee, ki tọkọtaya mii to nilo rẹ le lo o.

Ni ajọ NEDC si ni awọn onimọ nipa ọ̀lẹ inu obinrin ti gbe wọn jade kuro ninu amu nkan tutu, ti wọn si gbe wọn sinu obinrin mii ni ibẹrẹ ọdun yii.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, NEDC sọ pe ireti awọn ni pe iroyin yii yoo fun awọn eeyan mii ni igboya lati gba ẹyin ẹlomiran lo.

Awọn ibeji yii ni ọmọ akọkọ ti tọkọtaya Ridgeway bi pẹlu ilana IVF, lẹyin ti wọn ti kọkọ bi ọmọ mẹrin.

Ọkọ iyawo, Philip Ridgeway sọ pe ọmọ ọdun marun-un ni oun wa “nigba ti Ọlọrun da awọn naa, Lydia ati Timothy.

“O si ti n pa wọn mọ lati igba naa titi di asiko yii.”

Ọgbẹni Ridgeway sọ pe awọn ibeji naa ni ọmọ wọn to dagba ju, botilẹ jẹ pe awọn lo kere ju.

Ọjọ ori awọn ọmọ mẹrin ti wọn bi tẹlẹ wa laarin ọdun kan si ọdun mẹjọ.

Bawo ni lilo ẹyin ẹlomii fi bimọ ṣe n ṣiṣẹ?

Bi ida mẹrindinlogoji ninu ọgọrun, ni ẹyin ọmọ ti wọn ba gbà lo fi maa n di alaaye ọmọ ni America.

Ẹyin ọmọ le wa fun ọpọlọlọ ọdun, ti wọn ba ti gbe e sinu eroja nitrogen.

Koda wọn n fi ẹyin to ti lo ju ogun ọdun bi ọmọ.

Iye owo IVF kan ni America wa laarin ẹgbẹrun mejila Dọla, ẹyin rira si wa laarin ẹgbẹrun lọna ogun si marundinlogoji Dọla.

Ni Naijiria, owo IVF kan lati fi bimọ wa laarin miliọnu kan si miliọnu meji Naira. O si le ju bẹẹ lọ, nitori ileewosan kọọkan lo ni iye to n gba, eto ọtọọtọ si lo wa.

Awọn mii le lo ẹyin ti wọn, awọn miran le lo ẹyin ẹlomii.

Owo kekere kọ ni awọn to ma n fi ẹyin wọn silẹ ma n gba gẹgẹ bi owo iṣẹ.