Digbí ni ìdílé wa dúró- Toyin Abraham àti Kolawole Ajeyemi jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀

Toyin Abraham àti ìdílé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, TOYIN ABRAHAM/INSTAGRAM

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Toyin Abraham àti ọkọ rẹ̀, Kolawile Ajeyemi ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ tó gba ìgboro wí pé ìgbéyàwó àwọn ń la ìṣoro kọjá.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ ẹni tó ń mójútó ẹ̀rọ ayélujára Toyin Abraham 007globalmanagement ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé bí kò bá sì iná kò sí ohun tó ń jẹ́ èéfín àmọ́ ní ti ìròyìn pé Toyin àti ọkọ rẹ̀ ń fa àáwọ̀ irọ́ pátápátá gbá à ni.

Àtẹ̀jáde náà fi kun wí pé kò sí ìgbà kankan tí Toyin fi kọ̀ láti sun ilé láti ìgbà tí òun àti ọkọ rẹ̀ Kolawole ti fẹ́ ara wọn àyà fi tó bá wà ní oko eré.

Bákan náà ló ní ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ wí pé Toyin àti ọkọ rẹ̀ dìjọ máa ń lọ fún ìsinmi papọ̀ ni.

Ó ní àwọn fa gbogbo àwọn tó ń gbé ìròyìn irọ́ kiri lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti wí pé àwọn dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ti ń kọminú lórí ìròyìn náà láti ìgbà tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà ti jẹ jáde.

Àtẹ̀jáde náà fi kun wí pé kò sí ewu lóko àfi gìrì àparò wí pé digbí ni ìgbéyàwó Toyin àti Kolawole dúró ire.

Toyin Abraham àti Kolawole Ajeyemi

Oríṣun àwòrán, TOYIN ABRAHAM/INSTAGRAM

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Nínú ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kìíní, oṣù Keje ní gistlover fi sórí Instagram pé kí Toyin rọra tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́ nítorí ọkọ rẹ̀ ti ń rojọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí pé òun kò gbádùn ìyàwó òun.

Ó ní Kolawole ni òun kàn ń farada gbogbo àwọn ìwà àìtọ́ tí Toyin máa ń wù sí òun kódà ṣaájú kó tó bímọ àwọn.

Àtẹ̀jáde tí gistlover fi síta ni Kolawole fẹ̀sùn kàn wí pé ọ̀pọ̀ ìgbàni ìyàwó òun kìí sunlé, tí kìí sì ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

Toyin Abraham àti Kolawole Ajeyemi

Oríṣun àwòrán, TOYIN ABRAHAM/INSTAGRAM

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fọ́nrán tí Toyin máa ń gbé síta lórí Instagram máa ń jẹ́ ọgbọ́n láti fi bẹ òun nígbà tó bá ti wu àwọn ìwà tó máa ń wù.

Bákan náà ló ní Kolawole sọ fún onítọ̀hún wí pé kò sí ìgbéyàwó tó pé àti wí pé àwọn náà kàn ń dawọ́ bo ti wọn ni.

Èyí ni àwọn ohun tí Gistlover fi léde láti ṣèkìlọ̀ fún Toyin Abraham láti ṣe jẹ́jẹ́ kí ilé rẹ̀ má ba dàrú.

Ìmọ̀ràn gístlover yìí kò ṣẹ̀yìn bí ìgbéyàwó Funke Akindele àti ọkọ rẹ̀ JJCSkills ṣe forí ṣọ́pọ́n.

Nínú ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni JJCSkills kéde wí pé Funke Akindele ti lé òun kúrò nílé àwọn láti oṣù mẹ́ta sẹ́yìn .