
Oríṣun àwòrán, Tope Adebayo
Tope Adebayo, ti ọpọ eeyan mọ si Tope Maggie, ti fẹ wọ ìwé itan Guiness World Records gẹgẹ bi alase to dana ounjẹ fun wakati to pọ julọ lagbaaye.
Tope to jẹ ọmọbibi ilu Ogbomoso pinnu lati se ounjẹ fun igba wakati.
Irọlẹ Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni eto igbiyanju rẹ lati kọ itan tuntun fun awọn alase ninu iwe Guinness World orld Records rẹ bẹrẹ.
Igbiyanju Tope Maggie lati dana ounjẹ fun igba wakati yóò dopin ni aago mẹta ku iṣẹju mẹtadinlogun aarọ ọjọ Abamẹta lonii ọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun yii.
Ti ẹ o ba bagbe, laipẹ yii ni omo orileede Ireland kan, Alan Fisher, ti o ni ile ounjẹ ni Japan, gba ipo ẹni to se ounjẹ fun wakati to pọju lọ lagbaaye lọwọ Hilda Bassey ọmọbirin orilẹ-ede Naijiria nigba ti o ṣe ounjẹ fun wakati mọkandinlọgọfa.
Hilda ti saaju dana ounjẹ fun wakati mẹtalelaadọrun ki Fisher to pa akọsilẹ naa rẹ.
Apapọ ounjẹ to le ni irinwọ ni Tope se laarin ọjọ mẹwa naa ti eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹta jẹ ninu awọn ounjẹ naa.
Lara awọn to peju pesẹ nibi eto ina dida naa ni Honerebu Shina Abiola Peller to ti fìgba kan jẹ aṣoju ṣofin orilẹ-ede Naijiria ati Honerebu Akinwole Akinwale ẹniti o dije dupo sẹnetọ fun ẹkun ariwa ipinlẹ Oyo gbosuba fun Tope Maggie fun akitiyan rẹ.
Wọn rọ ijọba lati mojuto eto ti yoo ro awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria lagbara ati ti yoo mu idagbasoke baa orilẹ-ede.