Chinese tú Rọ́kẹ́ẹ̀tì ńlá sílẹ̀ tí yóò tó balẹ̀ s’áyé – Eko, New York àtàwọn ìlú míì ló leè jábọ́ sí

  • By Jonathan Amos
  • BBC Science Correspondent

Rọkẹẹti China

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkan lara awọn Rọkẹẹti nla orilẹede China ni wọn n reti ko bọ sori ilẹ aye nitori idi kan ti wọn ṣalaye pe airibi ṣamojuto irina rẹ.

Ni iwọn toonu mejidinlogun, ọkan lara awọn Rọkẹẹti to tobi ju fun ọpọlọpọ ọdun ni iwadii fihan pe o fẹ ṣi ọna yii.

Ilẹ Amẹrika sọ lọjọ Iṣẹgun pe awọn n woye ọna ti Rọkẹẹti naa ngba bọ ṣugbọn wọn ko ni erongba lati da ibọn bo o.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“A ni ireti pe yoo balẹ si ibi ti ko ti ni pa ẹnikẹni lara,” akọwe ileeṣẹ abo l’Amẹrika, Lloyd Austin lo sọ bẹẹ. “Ireti wa pe boya ninu ko balẹ sinu omi nla tabi iru ibi bayii kan naa”.

Oniruuru awọn akọṣẹmọṣẹ to n wo inu ofurufu n tọka si ọwọ irọlẹ tabi alẹ jọ Abamẹta tabi owurọ kutu ọjọ Aiku gẹgẹ bi akoko to ṣeeṣe ko balẹ.

Amọ, iru awọn iwoye bayii lee ma ri bẹẹ nigba miran.

Re-entry zone

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹrin gangan ni Rọkẹẹti “elliptical orbit” ti iwọn ibi to wa bayii to 160km si 375km ga ju aye lọ ṣugbọn to ti n kuna bayii.

Kí ni yoo ṣẹlẹ bi Rọkẹẹti yii ba balẹ si aye?

Gbogbo ọkọ lo yẹ ko fẹrẹẹ jona raurau nigba to ba fi gunlẹ latinu afẹfẹ, bo tilẹ jẹ pe o maa n ṣeeṣe ki o ni awọn irin to lee yọ́ lara atawọ́n afaragbaya mii ti yio fi ye bibalẹ rẹ.

Pe o ṣeeṣe ki apa kan tabi omiran lara ara rọkẹẹti ti yoo tuka ta ba eeyan ko fi bẹẹ ri bẹẹ, nitoripe ọp aaye lori aye lo jẹ omi nla ati pe apa ibi ti yoo balẹ si kii fibẹ jẹ ibi ti awọn eeyan n gbe.

The Aerospace Corporation

Oríṣun àwòrán, Twitter/The Aerospace Corporation

Wo Fọ́to Rọkẹẹ́ti China ọhun

Long March 5b rocket

Ki ni China sọ?

china ti fariga pe awọn eeyan n sọ pe awọn ko naani mimoju to iru nkan nla bayii to ṣina.

Awọn eeyan n gbe iroyin oniruuru ijamba ti iṣẹlẹ yii le ṣẹlẹ.

Ẹw, loju opo ayelujara orilede naa, wn ti ṣapejuwe awọn iroyin to n kari aye pe wọn kan n pọn n lasan ni. Ni tiwọn, wọn woye pe Rọkẹẹti naa ṣeeṣe ko balẹ sinu omi nla nla kan.