Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa – Yoruba/Biafra Nation

Oodua Nation

Oríṣun àwòrán, Others

Alaga Ajọ to n pe fun ominira fun ẹya to ba fẹ ya kuro ni Naijiria (Ninas), Ọjọgbọn Banji Akintoye ti fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn ti gba ọna ẹburu lati gbe ifẹhonu miran kalẹ tako awọn ni orilẹede Amerika.

Akintoye ni Ijọba Naijiria n san ẹẹdẹgbẹta dọla fun ọmọ adulawọ kọọkan ti wọn kii n ṣe ọmọ Naijiria lati ṣe ifẹhonuhan ni iwaju olu Ileeṣẹ Ajọ Iṣọkan agbaye ni New York, lorilẹede Amẹrika.

Loni tun ni ifẹhonuhan ẹgbẹ NINAS miran yoo waye nigba ti aarẹ Muhammadu Buhari yoo ma ba awọn adari orilẹede sọrọ.

Eleyii ko ṣẹyin bi ẹgbẹ awọn to n pe fun ominira Biafra ati Ilẹ Yoruba labẹ asia NINAS ṣe ti kede ifẹhonuhan lọjọ kan naa ti aarẹ Buhari yoo sọrọ ni ipade Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN.

”Olori ifẹhọnuhan wa yoo waye ni ọjọ ti aarẹ Buhari yoo ba Ajọ Iṣọkan agbaye sọrọ ni ilu Newyork to jẹ olu-ileeṣẹ wọn.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”A fẹ ṣe afihan iru ifiyajẹniyan ti ijọba aarẹ Buhari fi jẹ awọn ọmọ Naijiria, to fi mọ pipa ohun mọ awọn oniroyin lẹnu ati awọn iwa ajẹbanu miran labẹ aarẹ Buhari”

”Ohun ti a n beere fun ni ki idibo bẹẹni-bẹẹkọ gbogboogbo waye, ki awọn eniyan le sọ ero wọn lori boya wọn fẹ kuro lara orilẹede Naijiria abi bẹẹkọ.”

”Nitori irọ balau lo wa ninu we ofin Naijiria ọdun 1999, eleyii ti ko fun iwọ Guusu ati aarin gbungun Naijiria lanfaani lati ṣe nkan ti wọn ba fẹ, nitori ko si aṣẹ awọn araalu nibẹ.”

”Bakan naa ni a mọ wi pe ijọba Naijiria n sa gbogbo ipa wọn lati doju ifẹhọnuhan wa bolẹ, amọ ko si bi wọn ṣe ni owo to, wọn ko le e bori iṣejọba tiwantiwa.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”A mọ pe ijọba apapọ naa ti gbe ifẹhọnuhan ti wọn naa kalẹ ti awọn adari ni ijọba Buhari ati akọroyin kan to lorukọ ni ilu Eko, ti wa ni New Yorklati fun awọn eniyan ni owo, ki wọn ṣe ifọhọnuhan moriya fun aarẹ Buhari.”

Bakan naa ni ẹgbẹ Ninas fikun pe awọn ko ni mikan nitori igba gbọ awọn ni pe otitọ ni yoo leke pẹlu ifẹ araalu kii ṣe awọn aṣebi ati ika ni awujọ.

Ẹgbẹ to n pe fun ominira ilẹ Yoruba ati ilẹ Biafra naa ti kọkọ ṣe ifẹhnu ni Ọjọ Kẹrinla ati ikarundinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2021 ni Newyork ọhun ni igbaradi fun ipade Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN ọhun.