Alufa ijọ Katoliki Rev. Fr. Ejike Mbaka ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lori atimọle adari awọn eniyan to n ja fun ominira ilẹ Biafra, (IPOB), Nnamdi Kanu.
Mbaka sọrọ yii lẹyin ti o ti pada si ijọ Adoration rẹ ni Oṣu Kini ọdun yii.
Alufa Mbaka, nigba to n sọrọ lọjọ aiku wa kesi Aarẹ Buhari lati fun Nnamdi Kanu ni ominira nitori ti ko ba ṣe bẹẹ, abajade rẹ lee buru.
Father Mbaka sọrọ naa lasiko ti o n ba ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ ijọ Adoration rẹ sọrọ.
Nigba to n sọrọ lori ilakaka awọn ọmọ orilẹ-ede yii lati ri owo tuntun naa, Mbaka sọ pe ti Buhari ati Emefiele ko ba gbe igbesẹ lẹsẹkẹsẹ, wọn yoo ri ijiya.
O ni, “Ni Naijiria nikan ni ile ẹjọ le da ẹnikan silẹ, ti ijọba yoo si sọ pe ‘Rara’, ẹ ṣi fi si atimọle.
“Ẹyà Ibo n jìyà àìmọ̀”
“Ti Buhari ko ba tu Nnamdi Kanu silẹ, yoo kabamọ ipinnu rẹ”
Ninu adura rẹ, Mbaka sọ wi pe “A gbadura fun itusilẹ Nnamdi Kanu; ẹya Ibo n jiya fun ohun ti wọn ko mọ nkankan nipa rẹ.
Ọmọ ile iwe, oṣiṣẹ ko le lọ si ibi iṣẹ; ibi gbogbo ti wa ni titiipa ni awọn ọjọ Aje; awọn olori wa ko bikita; ko kan wọn”.
O tẹsiwaju o ni, “Ọlọrun sọ ẹnikan di ominira ati pe o sọ pe ẹni naa kii yoo ni ominira, ohun ti Ọlọrun yoo ṣe si ọ, iwọ yoo kabamọ ipinnu rẹ”.
Ninu ọrọ rẹ Mbaka rọ ijọba lati ṣe oun to yẹ o ni “awọn eniyan wa n jiya, ọpọlọpọ ijiya wa ni orilẹ-ede yii , Emi ki i ṣe oloṣelu, woli Ọlọrun ni mi. Ise mi ni lati sọrọ nigba ti Ọlọrun ba n binu,”
“Gbogbo ẹya to wa ni Naijiria lo n sọkun, ta ni adari wọn?”
Lori paṣipaarọ naira, o sọ pe ko si idalare fun ijiya ti awọn ara ilu n la kọja.
Mbaka sọ pe, “Awọn eniyan yoo jiya lati ṣiṣe owo wọn, wọn tun jiya lati gba owo wọn; Mo n fun Aarẹ ati Gomina CBN ni aṣẹ lati ọrun, ti wọn ko ba dẹkun laalaa ati idamu yii wọn yoo ri ijiya”.
Mbaka ninu ọrọ rẹ bẹ ijọba lati yipada, o ni, “Ijọba ti o wa lori oye lọwọlọwọ bayii , Mo fẹ beere lọwọ yin, ẹ yi pada, lai jẹ bẹẹ, awọn eniyan yin yoo sọkun”.
O ni “Awọn Hausa n sunkun; Fulani n sunkun; awọn Yoruba n sokun; awon Igbo n sunkun; Awọn ọmọ Niger Delta n sunkun, ta ni o n ṣe adari fun bayi?”.