Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!

Kayode Badru

Oríṣun àwòrán, Instagram/Celestialonline

Ariwo he lo jade lori ẹrọ ayelujara lẹyin ti ọdọmọde olowo ati oniṣowo ni ipinlẹ Eko, Kayode Badru ku iku ojiji ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ni ilu Eko.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹta, Osu Karun un, lasiko to n ṣe eto adura ninu ile ijọsin naa.

Ọkan gboogi ninu awọn agba ni ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye, Imolẹmitan Ojo ni ọpọlọpọ iroyin ofege lo n kaakiri lori iṣẹlẹ naa, ti kii si ṣe otitọ.

Kayode Badru jẹ ilumọọka ni ipinlẹ Eko, ti o si ṣẹ̀ṣẹ de lati Dubai wa si Naijiria lati wa ṣe ayẹyẹ to ti wa pin nkan fun awọn eniyan.

Bẹẹ si ni olu ilu ijọ naa to wa ni Dubai ni Kayode Badru ti n jọsin, ki o to wa si Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni iṣẹlẹ iku Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ ni ile ijọsin CCC?

Imolẹmitan Ojo to ba BBC News Yoruba sọrọ wi pe pẹlu ibanujẹ ni gbogbo ijọ naa wa pẹlu iṣẹlẹ iku Kayode Badru to jẹ ọmọ ijọ wọn.

Woli ati Oluṣọagutan ijọ naa, Ebony Felix mọ ara wọn ni nkan bi ọdun meji ṣẹyin, ti o si maa n gbadura fun un ni ọpọ igba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Brother Imọlẹmitan ni ọpẹ́ ní Kayode Badru ń ṣe pẹ̀lú imọlẹ meje ti o fi n ṣe ọpẹ naa ki o to di wi pe nkan yiwọ.

O ni: ”Funrara Kayode Badru lo tan imọlẹ meje to fẹ fi ṣe ọpẹ ni Ọsan Ọjọ Aje naa, ti o fi dupẹ lọwọ Ọlọrun

”Lẹyin naa ni wọn gba imọlẹ meje naa ni ọwọ rẹ, ti wọn si sunmọ kuro ni ọdọ rẹ, ki Woli Ebony to gbadura fun un to si wọn ‘perfume’ si i lara amọ ko pọju bi o ṣe yẹ lọ”

Kayode Badru

Oríṣun àwòrán, Google

Imolẹmitan ni: ”Amọ sutana fẹlẹfẹlẹ lo wọ si ara ti ko si si ẹni to mọ bi ina ṣe sọ ni ara rẹ”

”Ti ina fi jo Kayode ni ara ko ju iṣẹju aaya ọgbọn, ti ko si to iṣẹju kan ti awọn eniyan to wa nibẹ fi sare digbadigba lọ bu omi ti wọn si pa ina naa”.

”Wẹrẹ ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn si gbe e lọ si ile iwosan ijọba, ti wọn si tibẹ gbe e lọ si ileewosan ti wọn ti n tọju ijamba ina, to si bẹrẹ si ni gba itọju ni Ọjọ Aje ti iṣẹlẹ ọhun waye”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Arakunrin Imọlẹmitan tun ṣalaye fun BBC pe: ”Ni Ọjọ Iṣẹgun, ti mo lọ wo o ni ileewosan, alaafia ni o wa ti o si ba awọn eniyan sọrọ.”

”Ni Ọjọọru ti mo pada lọ si ibẹ, Kayode Badru sọ fun mi pe oun jẹun, o jẹ amala to si mu olomiọsan, amọ Ọjọbọ ni wọn sọ fun mi pe o ti jade laye”.

Ni bayii, olusọ naa ti wa ni atimọle ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti pẹlu awọn to wa nibẹ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ọhun.

Ẹ ṣọra fun aṣilo candle ati Pefume ninu ijọ mimo- CCC Worldwide

Lẹyin ti iṣẹlẹ yii waye ni atẹjade bọ sita lati ọdọ pasitọ agba ninu ijọ mimo lorilẹede Naijiria, Reverend Mobiyina Oshoffa wi pe ki awọn eniyan sọra pẹlu lilo oun eelo adura bii Candle ati perfume.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti kilọ fun awọn eniyan wi pe ki adari ẹsin wọn omi iyasimimọ si ara awọn eniyan ki wọn to wọn perfume.

CCC

Oríṣun àwòrán, CCC

Ki wọn si rii wi pe wọn da omi lu perfume ti wọn ba wọn si ara awọn eniyan ki agbara rẹ ma ba a pọju nitori o ni eroja ‘to le e gbina ninu.

Bakan naa ni wọn fikun un wi pe lati isinyii lọ ẹnikẹni to ba tako ofin naa ni awọn ile ijọsin yoo fi oju wina ofin.