Bàálù Peter Obi dé Ibadan fún ìpàdé àpérò àmọ́ kò le bà sí pápá Liberty

Peter Obi ati Ẹlikoputa rẹ

Rogbodiyan to n waye lori aisi epo rọbi ai ọwọn epo bentiroolu ti n nipa lori ọpọ araalu atawọn oloselu pẹlu.

Lọjọ Satide, ọjọ Kẹrin osu Keji ọdun 2023, ọrọ aabo to mẹhẹ nidi ọwọn owo ati Naira ọhun si ti n nipa lori eto ipolongo ibo Oludije aarẹ fẹgbẹ oselu Labour Party, Peter Obi.

Idi ni pe Peter Obi Peter Obi ko lanfani lati kopa ninu akanṣe apero ati ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ti seto kalẹ fun nilu Ibadan.

Ẹgbẹ awujọ kan, ‘South-West Development Stakeholders Forum (SWDSF)’ lo ṣe agbekalẹ ipade apero naa fawọn oludije si ipo aarẹ orilẹede Naijiria.

Lara awọn eeyan to si ti kopa nibi ipade apero naa oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu NNPP, Rabiu Kwankwaso ati akẹẹgbẹ rẹ fẹgbẹ oselu PDP, Atiku ABubakar.

Ibudo ipade apero ni Jogor

Ki lo de ti baalu Peter Obi ko fi raye ba silẹ nilu Ibadan?

Bi o tilẹ jẹ pe Peter Obi tete de silu Ibadan lati kopa ninu ipade apero naa lọjọ Satide yii ti wọn ya sọt fun amọ ko le bawọn kopa ninu eto naa.

Ni nnkan bii aago kan ọsan ni ọkọ ofurufu ẹlikoputa to gbe Peter Obi, de si Ibadan, ti o si n wa ibi ti yoo ba si.

Gbogbo igbiyanju lati jẹ ki baalu kekere naa ba si papa iṣere ‘Liberty Stadium’ lo ja si pabo nitori pe awọn alakooso ibẹ sọ wi pe ko si aye fun ọkọ ofurufu naa.

Lyin o rẹyin ni awọn alakoso ipade apero naa sọ fun oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour naa pe ko mase ba silẹ mọ, amọ ko pada sibi to ti n bọ.

Idi ni pe aabo mẹhẹ nilu Ibadan lọjọ Satide naa, ti eto alaafia gbọngan igbalejo ‘Jorgor Centre’ to n bẹ ni agbegbe Ring Road ni Ibadan, to yẹ ki ipade apero naa ti waye ni alaafia rẹ ko fi bẹẹ rọgbọ.

ibudo ipade apero ni Jogor

Ni ọjọ Satide ti wọn fi ipade apero naa si, si ni iwọde n lọ lọwọ ni aarọ ọjọ Satide naa lagbegbe Apata eyi to mu ẹmi eeyan kan lọ.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan ti joko si gbọngan ipade apero naa lati gbọ ohun ti Peter Obi fẹ sọ, to fi mọ akọroyin fun BBC Yoruba.

Amọ ipade naa ko le waye nitori aifararọ eto aabo naa.

Ọkan lara awọn aṣoju SWDSF ti o ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipejọpọ naa, Adedayọ Alao ṣe alaye wi pe, rogbodiyan to waye nilu Ibadan saaju ọjọ naa lo sokunfa wiwọgile ipade apero naa.

O ni awon eeyan kan n fi ọhonu han lori ọwọn gogo epo bentiro ati aisi owo tuntun n’igboro.

Alao ni eyi si lo faa ti Obi ko ṣe dẹsẹ duro nibi apero naa rara.