Àwọn tí wọ́n ò tíì bí bàbà wọn nígbà tí mo gbé Tinubu jáde ló ń bú mi pé mò ń jowú rẹ̀ – Ayo Adebajo

Ayo Adebanjo ati Peter Obi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Adari ninu ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ti sọ oko ọrọ sawọn to n wa ọrọ lee lori tori ibi to to si lori taa ni yoo jẹ aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party Ọgbẹni Peter Obi ati igbakeji rẹ Sẹnetọ Yusuf Datti Baba-Ahmed gbe ipolongo ibo wọn lọ si Ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo lana Ọjọru nibi to ti sọrọ ba awọn to n bu ẹnu atẹ lu u lori.

Adari ẹgbẹ Afenifere tii ṣe ti awọn ọmọ Yoruba oloṣelu, Oloye Ayo Adebanjo rọjo ọrọ sawọn to ti n fesi sii lori iduro rẹ latọjọ yii gbagba lẹyin Peter Obi oludije Labour Party.

Ipolongo idibo Peter Obi ni Ibadan

Ipolongo naa to waye ni ọjọ Kẹtalelogun Oṣu Kokanla Ọdun 2022 ni Papa isere Lekan Salami ipinlẹ Oyo ni ọrọ ti oloye Ayo Adebanjọ sọ nipa Peter Obi ti han jade.

Adebanjo sọ kobakungbe ọrọ si awọn eeyan kan bo tilẹ jẹ pe ko tọka tabi darukọ ẹnikẹni.
“Gbogbo awọn ti wọn o tii bi baba wọn nigba ti mo gbe Tinubu jade fun ipo gomina ni wọn n sọrọ pe mo n jowuu Tinubu ni.”

Adebanjo ni ọrọ Nigeria ki n ṣe ọrọ̀ Yoruba ati Igbo nikan, “ọrọ gbogbo wa ni, ki Yoruba ṣe ki Hausa ati Igbo naa ṣe ni Nigeria le fi dara.”

Adebanjo ṣalaye nigba to n sọrọ nibi ipolongo naa pe Oloye Olusegun Obasanjo lo gba ipin ti Yoruba ti Yaradua ati Buhari si ti gba ti ilẹ Hausa.

“Ibeere mi lọwọ gbogbo awon ti wọn ni mo n jowu Tinubu ni pe ṣe Yoruba lo tun kan? Awọn Igbo nkọ, nitori idi eyi ni ẹgbẹ Afenifere ṣe ṣe atilẹyin fun Peter Obi ki a le pin in daada.”

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ni egben jẹgbe ni Iwo-Oorun orile-ede Nigeria ati awon oloye ẹgbẹ naa lo peju pesẹ sibi eto naa, bakan naa ni agba ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ko awọn oloye ẹgbẹ Afenifere dani nibi eto naa.

Ayo Adebanjo ati Peter Obi

Ki ni Adebanjo sọ fawọn alatako rẹ?

Ayo Adebanjo

Nigba ti o n ba awon eniyan sọrọ, Oloye Adebanjo fesi si gbogbo ọrọ ti awon kan sọ pe o n jowu oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ni.

O wipe “gbogbo awon ti wọn o tii bi baba wọn nigba ti mo gbe Tinubu jade fun ipo gomina ni wọn sọrọ pe mo n jowu Tinubu”.

Bakan naa ni oludije sipo aare lẹgbe oselu naa Peter Obi sọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party maa mu igbe aye dẹrun fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijria ati pe oun maa duro lori idajọ ododo ti oun yoo si fi ibẹru Ọlorun ṣe akọkọ ni gbogbo ohun ti oun ba dawọ le nidi eyi gbogbo ohun to ti daru ni orile-ede Nigeria ni oun maa tun ṣe pada.

Lẹyin eyi ni alaga ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni orile-ede Naijria Ọjogbon Julius Abure gbe asia ẹgbẹ fun oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo Ọgbeni Taofeek Akinwale lati fi atilẹyin wọn han fun un ni ipinlẹ rẹ.