Àwọn ọ̀nà tí òfin tuntun CBN lórí Bureau De Change tí wọ́n gbé’gi lé ṣe kàn ọ́

Central Bank Policy on BDC: Àwọn ọ̀nà tí òfin túntun CBN lórí Bureau De Change ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lánàá òde yìí ní ìjọba Nàìjíria kéde pé òun yóò fi òfin dé ìpa àwọn to n máa n ṣe àyípada owó Dọ́là àti Pọ́ùn nígboro.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké gbàjarè pé wàhálà ńla ní ọ̀rọ̀ yìí yóò dá sílẹ̀ fún àrá ìlú ní orílẹ̀edè Nàìjíríà.

Kódà àwọn mííràn ní èyí yóò tún mú kí ètò ọ̀rọ̀ ajé tí ó tí n dẹnu kọlẹ̀ tẹ́lẹ̀ tún búrú jáì síi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ajé ni Nàìjíríà tó tún jẹ́ Agbẹjọ́rò , Adebisi Iyaniwura ṣàlàyé pé gbogbo ìrètí kò tíì tán lọ́rí ọ̀rọ̀ náà tí ìjọba bá ṣetan láti ṣe òótọ́ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ará ilú.

O ní sáájú àsìkò yíì tí ìjọba fi dá àwọn tó n ṣẹ owọ ilẹ̀ òkèrè yìí ni láti mú kí nǹkan rọ̀rùn fún àwọn ará ìlú tó bá fẹ́ rín ìrìnàjo lọ sí ilẹ̀ òkèrè tí wọ̀ kò sì nílò owó tí o’pọ̀ jù.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ àwọn ènìyàn wọ̀nyìí gan ló wá n fí owó náà ṣe nǹkan ti kò ta tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni tàá dọ́là fún àwọn ti kò ní ẹ̀tọ́ síi.

Onímọ̀ nípà ètò ọ̀rọ̀ ajé náà ní ọ̀ṣẹ̀ọ̀sẹ̀ ni ilé ìfowópamọ̀ sí apapọ máá n fún Bureau De Change ni ẹgbẹ̀run lọ́nà ogun dọ́là sùgbọ́n wọn kòi mọ̀ ibí ti owó náà ń wọlẹ̀ sí nítori ọ̀pọ̀ ènìyàn kò rí ìrìnajo lọ sí ilẹ̀ òkèrè mọ́.

Tí ẹ̀ kò bá gbàgbé CBN pẹ̀lú ni àwọn gan ló ń ran àwọn tọ n kó owó pamọ́ lónà àìtọ́ lọ́wọ́.

Iyaniwura ni báyìí, o ti dẹrun fún àwọn ènìyàn tó nílò owó tíí kìí ṣe pé wọ́n fẹ́ ko pamọ̀ kí o le wúlò fún wọn.

Irú ìwà báyìí gan wà lára ìdí tí owó Nàìjíríà kó fi ní ìyì kankan mọ́

Anfààni tó wà nínú ìgbésẹ̀ ìjọba tuntun yìí

Igbésẹ̀ yìí yóò jẹ́ kí àwọn tó nílò owó dọ́là ní tòótọ́ rí owó ló fún ìrìnajo tàbí ríràn ọmọ lọ sí ilé ìwé

Nàìra Nàìjíríà yóò ni ànfani láti mí: nítori pé ọ̀pọ̀ ló ti rí owò dọ́là bí òwò tí ó ni owó lórí, wọ́n máá n ra dọ́là pamọ, èyí yóò fi òpin sí i.

Kò ní sí ìbi ti àwọn ilé ìfowopamọ sí láti má fún ará ìlú ni dọ́là tí wọ́n bá nílò láti rin ìrìn ajò.

Ó wá rọ ará ìlú láti ni ìgboye nínú owó Nàìrà, kí wọ́n sì yé ra dọ́là pamọ́ sílé mọ́, èyí tí ọ̀pọ̀ ti sọ di òwò òòjọ.

Bákan náà ló tún fi kú pé àwọn olùṣòwò BDC tí wan lọ máa nṣe àdàmọdì ìwé láti fún CBN nípa àwọn tó wá gbá dọ́là yóò wá sí òpin.

Ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ náà ní ó ṣe pàtàkì kí ìjọba ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ láti rí pé àwọn ènìyàn ní ìgbàgbọ́ ninu àwọn ètò ìjọba, kí wọ́n si wo gbogbo ìbi ti ihò le wà.

Ó ní kí àwọn asojú ìjọba máa fi àsìkò yìí gbé gbogbo ìpàdé àti ojúṣe wọn lọ si ilẹ̀ òkèrè láti lé maa ni ànfàni láti gba dọ́là ti wọ́n yóò ko pamọ́.

“Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn olóṣèlú ni àwọn ilẹ̀kùn ti wọ́n yóò kan tó sì jọ́ pé àwọn nìkan ni yóò ma jẹ àǹfàni tí àwọn mẹ̀kúnù yóò sì má jìyà rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ