Àwọn ọ̀dọ̀ fẹ̀hónú hàn n‘Ibadan, agbófinró tú wọn ká

Ifehonuhan

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA

Ọgọọrọ awọn ọdọ lo n tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan lori bi ilu ko ṣe fi ara rọ, ti iwọde si waye ni ẹnu ọna yunifasiti ti Ibadan nipinlẹ Oyo.

Awọn ọdọ naa lo pejọ lati fẹhonu han lori rudurudu eto-ọrọ aje to n lọ ni orilẹ-ede yii.

Awọn ọdọ naa ni wọn ti wọgi di ẹnu-ọna ile-ẹkọ Faṣiti Ibadan ti wọn si di igokegbodo ọkọ ati awọn iṣẹ miiran lọwọ laarọ oni.

BBC Yoruba ri pe awọn ọmọ ogun ati awọn oṣiṣẹ Operation Burst yabo ibi iwọde naa.

Ninu fọnran aworan kan to tẹ BBC Yoruba lọwọ, ọpọlọpọ awọn ọlọpa ati awọn oṣiṣẹ ile iṣe ologun orilẹ-ede yii ni wọn wa nibẹ iwọde naa.

Ifehonuhan

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA

Awọn akẹkọọ fasiti Ibadan ko si lara awn ọdọ to n fẹhonu han – Agbẹnusọ fun fasiti Ibadan

Aṣoju Faṣiti ibadan , Iyaafin Adejoke Akinpelu, sọ fun awọn akọroyin pe awọn oṣiṣẹ alaabo ti tu awọn ọdọ to n fẹhonu han ka.

O ni, “Olori ẹka aabo Faṣiti U.I sọ fun mi pe awọn kan ni agbegbe yii ti wọn ko ara wọn jọ si ẹnu- ọna Faṣiti ni owurọ yii, ni wọn n fa wahala.

Awọn ọmọ ile-iwe wa n joko fun idanwo wọn, wọn ko ṣi lara awọn ti o n ṣe ifẹhonuhan.

Wọn tun sọ fun mi pe awọn ẹso alabo to wa, ti tu wọn ka.”

Ifẹhonuhan yii ko sẹyin rogbodiyan epo ati inira awọn ọmọ orilẹ-ede yii lati ri owo naira gba ni awọn ile ifowopamọ kakakiri orilẹ-ede yii.

UI protest

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA