Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!

Obinrin to wa ni ihoho

Oríṣun àwòrán, James D. Morgan

Awọn ẹgbẹ kan ni awọn ọlọpaa Dubai fi panpẹ mu pe wọn fi ihoho wọn han ni ita gbangba nibi ti wọn ti n ya foto.

Fọnran kan ti wọn fi sita lori ayelujara lọjọ Satide ni o ṣafihan awọn ọmọbinrin kan to wa ni ihoho ti wọn n ya fọto ara wọn lori aareni ilé kan.

Eti omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mọkanla ninu awọn eniyan ti wọn mu ni ọmọ Ukraine, ti olu ilé iṣẹ Ukraine si sọ fun BBC pe àwọn ọmọ orileede Russia naa wa lara wọn gẹgẹ àwọn ile iṣẹ iroyin Russia ṣe sọ.

Ẹwọn oṣu mẹfa tabi ṣisan ẹgbẹrun marun dirham (£981) ni ijiya fun iru ẹsẹ ki eniyan maa farahan ni ihoho nita gbangba.

Ọpọ awọn ofin UAE jẹ ti Sharia ti ọpọ si ti wọ ẹwọn latẹyin wa nitori pe wọn sì ihoho wọn sita tabi wọn ni ifẹ akọsakọ tabi abo Sabo.

Ogunlọgọ awọn obinrin ni o han ninu aworan naa ti wọn ya foto lori baakoni ni agbegbe Marina ni Dubai.

Olule iṣẹ Ukraine ni oun yoo ṣabẹwo si awọn obinrin naa lonii, ọjọ Isẹgun.

Saaju ni iroyin ti gbe e ni awọn ile iroyin Russia pe ọmọ Russia mẹjọ ni wọn mu, sugbọn ile iṣẹ iroyin Ria ni awọn ọmọ Russia to sagbekalẹ eto naa ni wọn ti fi panpẹ ofin mu

Yoo koju ẹwọn ọdun kan abọ gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ọlọpaa Dubai ti kilọ pe ẹnikẹni to ba n ṣe sinima onihoho to si gbe e sita gbangba yoo koju ẹwọn ati owo itanran.

“Iru iwa ibajẹ bayii ko safihan iwa awọn eniyan Emireeti” gẹgẹ atẹjade ọlọpaa ṣe sọ.

Gbogbo ẹnikẹni to ba n gbe tabi ṣabẹwo si UAE, gbọdọ tẹle ofin, ko si si agbeyẹwo kankan fun awọn arinrin ajo afẹ pẹlu.

Ko wọpọ ki awọn arinrinajo afẹ bọ sinu wahala to niṣe pẹlu ofin ti wọn yoo fi fi panpẹ ofin mu wọn lasiko isinmi ni Dubai.

Lọdun 2017, obinrin ọmọ ilẹ gẹẹsi kan lọ ẹwọn ọdun kan tori o ni ibalopọ pẹlu ọkunrin kan tii kii ṣe ọkọ to fẹ ẹ niṣu lọka. Asiri ibaṣepọ wọn nigba ti obinrin naa lọ fẹjọ sun pe ọkunrin ọhun n dunkoko iku mọ oun.