Àwọn dókítà gbé ọ̀bẹ jádé nínú ilé ọmọ obìnrin kan lẹ́yìn ọdún 11 tó ṣiṣẹ́ abẹ

Awọn dokita kan ninu yara iṣẹ abẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun ọdun mọkanla ni Arabinrin Felistah Nafula, ẹni ọdun mẹrindinlogoji fi gbe pẹlu ọpọ irora ni inu ikun rẹ pẹlu ero pe ọgbẹ inu lo n da oun laamu.

Felistah wa itọju titi laisi ọna abayọ to yọju lakoko.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ pe irora yii bẹrẹ lẹyin to se diẹ ti wọn fi iṣẹ abẹ gbẹbi rẹ nigba to fẹ bi akọbi rẹ ni ile iwosan kan ni Kitale, lorilẹede Kenya.

Bi ọdun ṣe n gori ọdun ni irora naa n peleke sii, ti awọn dokita si n woye pe ọgbẹ inu ‘ulcer’lo n da a laamu.

Nigba ti wahala yii n ṣe kẹrẹkẹrẹ wọ ọdun kejila, lawọn dokita ba bẹrẹ si ni woye pe o fẹ dabi ẹni pe ohun to n ṣẹlẹ si arabinrin naa fẹ ju ti ọgbẹ inu lọ.

“Wọn ba ọbẹ iṣẹ abẹ naa ninu ikun arabinrin ọhun, nibi to fara pamọ si laarin ile ọmọ rẹ ati ifun rẹ”

Ọpọlọpọ aworan ayẹwo inu ti wọn bẹrẹ si ni ṣe fun un n fihan pe, nnkan kan bii irin wa ni inu rẹ.

Eyi lo mu ki wọn ni ko ṣe iṣẹ abẹ lati mọ nnkan gan to wa ni inu rẹ.

Lẹyin iṣẹ abẹ oni wakati meji ọhun to waye lọjọ keji oṣu keji ọdun 2023, ni awọn dokita fi han an pe ọbẹ iṣẹ abẹ ni wọn ba ni inu rẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe Dokita Kairo Kimende, to jẹ adari agba fun ile iwosan Marauga Level four hospital ni agbegbe Muranga ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ naa, lọjọbọ sọ pe, wọn ba ọbẹ iṣẹ abẹ naa ninu ikun arabinrin ọhun, nibi to fara pamọ si laarin ile ọmọ rẹ ati ifun rẹ.

Abẹ naa ti duro si aye ti yoo fi ‘soro pupọ fun arabinrin Nafula naa lati loyun lati igba ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ ọhun.”

Arabinrin Nafula ni abẹ naa fẹrẹ tu igbeyawo oun ka nitori ọkọ oun ko mọ idi ti oun ko fi loyun miran lẹyin akọbi awọn.

‘Mo lero pe ijọba yoo le ṣe iwadi awọn dokita to ṣiṣẹ abẹ naa lori ọrọ yii’

Mo mọ pe nnkan n ṣe aya mi ṣugbọn ko sọ si mi lọkan pe o le nii ṣe pẹlu ọrọ airi oyun ni rẹ – Samuel Mungai

Gẹgẹbi iroyin ti awọn ileeṣẹ abẹle lorilẹede Kenya gbe sita, ọkọ arabinrin yii, Samuel Mungai ni ọkan oun balẹ ni gbogbo igba ti iṣẹlẹ naa fi n ṣẹlẹ nitori pe oun nifẹ iyawo oun gidigidi.

“Mo tilẹ ko ipa ribiribi lati rii pe mo gba itọju iṣegun oyinbo to jọju fun un.

Kii ṣe lati ri ọmọ bi, ṣugbọn lati ri ojutu si iṣoro irora inu to n ṣe e, to tilẹ maa n mu ko daku nigba miran.

Mo mọ pe nnkan n ṣe e ṣugbọn ko sọ si mi lọkan pe o le nii ṣe pẹlu ọrọ airi oyun ni rẹ.”

O ni oun lọ si ọdọ dokita kan lati mọ boya oun ni okunfa airi oyun ni iyawo oun.

“Pẹlu oye ti mo ni pe o seeṣe ko jẹ pe iyawo mi ni o ni iṣoro, ni mo ba fi tubọ mojuto ọrọ rẹ.

Awọn ọrẹ mi to jẹ dokita sọ fun mi pe ki n gbe iyawo mi lọ ṣe oniruuru ayẹwo to nii ṣe pẹlu ati le bimọ rẹ.”

Aworan abẹ ti wọn gbe jade ninu ikun arabinrin naa

Oríṣun àwòrán, Victor Kinuthia/facebook.com

“Ireti mi ni pe awọn dokita yoo sanwo gba maa binu fun wa tori wahala ati irora ti wọn da si wa lọrun”

Aworan ara X-ray ti wọn ṣe ni ọkan lara awọn ile iwosan to lọ ni ilu Thika fihan pe, nkankan wa bi irin ninu ikun rẹ.

Inu arakunrin Mungai dun pe iyawo rẹ ti bọ lọwọ iṣoro abẹ to n gun un ninu yii.

Kii ṣe ati bimọ gan ni olori ọrọ, bi o ba si waye o, a jẹ pe ogo ni fun Ọlọrun.”

O ni ireti oun ni pe awọn dokita yii san owo gba maa binu fun awọn nitori wahala ati irora ti wọn da si awọn lọrun.

“Mo gbagbọ pe ijọba yoo ṣewadii awọn dokita to ṣe aṣiṣe lasiko iṣẹ abẹ ti wọn fi gbẹbi iyawo rẹ lọdun mọkanla sẹyin, ki wọn lee ṣalaye bi wọn ṣe ṣe e ti wọn gbagbe abẹ si inu iyawo mi.”