Ariwo sọ pé Aunty Ramota ṣe iṣẹ abẹ láti fọn idi, ó ti dákú láì jẹ́ aráayé tàbí èrò ọ̀run, Ijoba Lande ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́

Ramota wa nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iroyin agbọyanu ni iroyin kan to n sọ nipa ipo ti ilera gbajugbaja oṣere tiata, Ramota Adetu, ẹni tí ọpọ mọ si Aunty Ramota wa, lẹyin ti iroyin kan jade pe o ṣe ìsẹ abẹ lati fọn idi rẹ.

Ọpọ fọnran lo ti gba ori ayelujara, paapa eyi to safihan bí wọn ṣe n gbe Aunty Ramota wọ yara itọju nile iwosan.

Iroyin to n lọ lori ayelujara ni pe Aunty Ramota ṣe iṣẹ abẹ lati fón idi rẹ ko le tobi si eyi ti oloyinbo n pe ni BBL, ni ile iwosan kan ni Ìkorodu.

Aworan Aunty Ramota

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọ̀pọ̀ osere sọ̀rọ̀ nipa iroyin isẹ́ abẹ naa…

Kii se igba akọkọ ree ti iroyin gbalẹ pe Aunty Ramota ṣe iṣẹ abẹ idi yoo lu síta lori ayelujara.

Awọn eeyan kan, paapa awọn ololufẹ oṣere tiata naa kọ lati gba iroyin naa gbọ, ti wọn si sapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ere sinima.

Bakan naa ni ọpọ awọn akẹgbẹ Aunty Ramota nidi isẹ ere sinima ni awọn gbagbọ pe ere sinima ni iroyin nípa isẹ abẹ idi BBL ti wọn ni Aunty Ramota ṣe.

Toyin Lawani sọrọ lori opo ayelujara ; “Ere sinima ni, ẹ gbagbe, n ko le gba eyi gbọ.

“Bawo ni idi ṣe fẹ rí lori ẹsẹ rẹ. Awada lasan ni, ko si Dokita ti yoo se isẹ abẹ naa.”

Aunty Ramota nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ijoba Lande tan imọlẹ si iroyin to ni Aunty Ramota ṣe iṣẹ abẹ fifọn idi BBL

Ibeere yii lo mu ki BBC Yoruba kan si Ganiyu Kehinde Morufu, ẹni tí ọpọ mọ si ijọba Lande lati imọlẹ si ọrọ naa pe ṣe loootọ ni Aunty Ramota ṣe iṣẹ abẹ idi BBL nile iwosan.

O salaye pe ohun iyalẹnu ni iroyin naa jẹ fun oun nigba to gbọ nípa rẹ ati irọ to jina si otitọ ni iroyin naa.

Ìjọba Lande ni inu ko dun sì bí iroyin naa lu síta nitori ere sinima lasan ni.

“Inu n bi lọwọ nitori mo kan si Aboki to wa pẹlu Ramota pe ṣe fọnran yii ki ṣe ere, o ni ki ṣe ere.

“Mi o ni anfani lati sun mọjumọ nitori nigba ti mo kọkọ rí fọnran naa, n ko gbagbọ ti awọn eeyan sì n pe mi lati mọ nnkan to sẹlẹ.

“Emi ati Ramota o gbe papọ sugbọn a jọ ma wa pọ ni ọpọ igba.

“Mo igbiyanju lati se iwadi sugbọn pabo lo jasi, mo wa kan si ọrẹ Ramota kan lori Ayelujara Instagram pe ki lo sẹlẹ, mo bẹ ko sọ fun mi boya ere abi otitọ ni fọnran yii.

“Nigba to di arọ yii ni Mummy Aunty pe mi lati salaye pe ere ni gbogbo ohun to lu síta lori ayelujara.

“Mo ní ọrọ iru ọrọ bayii ko ki n ṣe ere rara. Gbogbo nnkan ti ẹ rí pata, ere sinima lasan ni “

Aunty Ramota

Oríṣun àwòrán, auntyramota_authentic/Instagram

Ta ni Aunty Ramota?

Ramota Adetu, ti ọpọlọpọ maa n pe ni Aunty Ramota jẹ ọmọ bibi ilu Ikorodu nipinlẹ Eko, ọdun 1981, eyiun ọdun mẹtalelogoji sẹyin ni wọn bi sile aye.

Amọ Aunty Ramota ni aisan kan lara eyi ti ko jẹ ko dagba soke, to si ri kekere bi ọmọde, ti ko si dabi agbalagba rara.

Ọdun mẹta sẹyin ni mama Ramota ku, ti ko si si ẹni to mọ nipa baba rẹ.

Osere tiata ni Ramota, to si tun maa n dẹrin pa osonu.

Bo se da bi ọmọde lo mu ki ọpọ eeyan nifẹ lati wo, to si maa n se ọmọ ile ẹkọ pẹlu gbajumọ adẹrinposonu miran, Ijaba Lande.

Lara ere ti Ramota ti kopa ni fiimu Ọkọ Ramota ati sinima Anikulapo apa keji.