Arìnrìnàjò 54 pàdánù ẹ̀mí wọn nínú Ìjàmbá ọkọ̀ lánàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, FRSC

O to arinrinajo mẹrinlelaadọta to padanu ẹmi wọn, ti ọpọlọpọ si farapa yanayana lẹyin ti oniruuru ijamba ọkọ waye lọjọ kan naa lorilẹede Naijria.

Ijamba ọkọ ọhun lo waye ni ana ọjọ kejidinlodun oṣu kẹwaa ọdun 2022,  ni olu ilu orilẹede yii, Abuja ati ni opopna ọna Maiduguri si Damaturu.

Obinrin ati ọmọde wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ lẹyin ti awọn ọkọ ayọkẹlẹ kọlu ọkọ ajagbe tipa lopopona naa.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ to n risi irinna FRSC, Bisi Kazeem ni ọkan lara isẹlẹ ijamba ọkọ naa waye ni owurọ ọjọ Isẹgun lopopona Kwali- Abaji niluu Abuja.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ arìnrìnàjò jóná kọjá mímọ̀

“Iwadii wa fihan pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ọkọ tipa pẹlu nọmba idanimọ BAU 632 XA ati ayọkẹlẹ pẹlu nọmba idanimọ GME 201 ZU kọlu rawọn,”

O fi kun pe arinrinajo mẹjilelogun wa nibi iṣẹlẹ ijamba naa ṣugbọn mejidinlogun ni awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, ti gbogbo wọn si jẹ ọkunrin

Awọn mẹrin ni awọn toku farapa yanayana, ti ọkan lara awọn ko si fi ara pa rara.

Nibi iṣẹlẹ keji, eeyan metadinlogoji lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti bọọsi ero meji kọlu arawọn

Kazeem ni kete ti wọn kọlu arawọn ni ina ṣeyọ lopopona Maiduguri si Damaturu.

O ni ọpọlọpọ arinrinajo lo jọna kọja mimọ ninu iṣẹlẹ naa.

Kí ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọ̀hún?

Ileeṣẹ to n risi irinna FRSC ni nnkan to fa iṣẹlẹ ijamba ọhun gẹgẹ bii iwadii wọn ṣe sọ ni o jẹ ere aṣapajude ati pe o ti rẹ awọn awakọ naa.

Ninu atẹjade ti wọn fi ransẹ si awọn akọroyin, FRSC ni awọn ti ko awọn to farapa lọ si ile iwosan Abaji fun itọju, ti wọn si ti gbe awọn oku lọ sile oku.

Ọga agba fun ileeṣẹ ọhun, Dauda Ali Biu hdon ti wa rọ awọn awakọ lati yago fun ere aṣapajude ati irin alẹ.

O rawọ ẹbẹ si awọn awakọ lati maa simi lẹyin wakati ti wọn ba ti n wa ọkọ, eyi to ni yoo fun wọn lafani lati simi daadaa.