APC ṣàlàyé ìdí tí ìpolongo ìbò Tinubu tó yẹ kó wáyé ní Ibadan, kò fi le wáyé mọ́

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @BATofficial

Ẹgbẹ oṣelu APC tí sun ìpolongo ibo aarẹ to yẹ ko waye loni nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo siwaju.

Eyi ko sẹyin bí iwọde ṣe n waye lori ọwọn gogo epo ati bi owo naira to safẹrẹ ni agbegbe naa.

Ikede naa waye lọjọ Aje, ọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun 2023.

Tinubu lo yẹ ko gbe ìpolongo ibo aarẹ wa siluu Ibadan loni sugbọn bii nnkan ṣe lọ ní ìpínlẹ naa lọwọ lọwọ bayi, ni igbagbọ wa pe o sokunfa idi ti ẹgbẹ oṣelu APC fi sun ipolongo ibo naa siwaju.

A sun ipolongo ibo Tinubu siwaju tori laasigbo tí Naijiria n la kọja lasiko yii – APC

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC, Wasiu Sadare, fi lede fun awọn akọroyin, ó salaye idi ti APC se sun ipolongo ibo naa siwaju.

APC ni torí bi ọwọn gogo epo bentiro ati bí owo naira ṣe nira lati ni fun awọn ọmọ Orilẹede Naijiria lo fa tí awọn fi gbe igbesẹ naa.

“Ẹgbẹ oselu APC tí sun ìpolongo ibo aarẹ tí ipinlẹ Oyo siwaju.

“A gbe igbesẹ yii nítorí gbogbo laasigbo tí awọn eeyan ipinlẹ naa ati Orilẹede Naijiria n la kọja lasiko yii.

“Aarẹ Muhammadu Buhari nilo akoko lati wa ojutu sì gbogbo rogbodiyan naa, kí alaafia sì pada.”