Amotekun àtàwọn jàndùkú kọlu ara wọn ní Ibadan, èèyàn méjì kú lọ́jọ́ Ileya

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Awọn oṣiṣẹ ikọ Amotekun kan ti yinbọ pa eeyan meji nigba ti eeyan kan farapa lagbegbe Oke-Ado, niluu Ibadan.

Iroyin fi orukọ awọn eeyan meji naa lede gẹgẹ bii Ishola Abdullahi ati Rasheed Mushidaru, ti ẹni to farapa n jẹ Alaba Isah.

Lasiko to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye fun awọn akọroyin, ẹgbọn Abdullahi sọ pe awọn ọdọ adugbo korajọ si agbegbe Ajanla lẹba papa Isere Liberty lati ṣe ọdun Ileya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni epo bẹntiro tan ninu ẹrọ amunawa ti awọn n lo lo gbe wọn lọ sile epo lati ra epo, aburo oun si tẹle awọn.

“Ṣugbọn ko to iṣẹju marun un ti a fẹ lọ ra epo naa ti a ri awọn ikọ Amotekun ninu ọkọ wọn ti wọn si bẹrẹ sin n yinbọn si wa.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“A ko ba ẹnikẹni ja, koda a pade awọn ọlọpaa lọna ti ko si iṣoro kankan titi di igba ti a ri awọn ikọ Amotekun naa ni orita J-Allen si Molete, eyii to mu gbogbo wa tuka.”

O ni lẹyin ti awọn ikọ Amotekun naa lọ tan ni awọn ri oku Abdullahi nilẹ ninu agbara ẹjẹ.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, wọn gbe Abdullahi digba-digba lọ sile oniṣegun kan ko le yọ ọta ibọn naa lara rẹ, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Nigba ti ẹni to duro gẹgẹ bii baba fun Abdullahi, Alhaji Olayiwola Sulu Ishola, ti ọpọ mọ si Alhaji Salala n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ori ẹrọ ilewọ ni wọn ti ke si oun pe awọn Amotekun ti ṣekupa ọdọkunrin naa.

Salala ni “Awọn ọmọkunrin naa n ṣajọyọ ọdun lọwọ ni ki awọn Amotekun to bẹrẹ si n yinbọn si wọn.”

O ni “Awọn ọmọkunrin tuka ki ọta ibọn ma ba ba awọn, ṣugbọ ibọn ba ibatan mi ti oun ati ẹlomiran si padanu ẹmi wọn.”

Alhaji Salala pari ọrọ rẹ pe awọn ti sin oku Abdullahi gẹgẹ bii alakalẹ ẹsin Musulumi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, nigba ti awọn akọroyin kan si adari ikọ Amotekun ni ijọba ibilẹ Guusu Iwọ oorun Ibadan, Sikiru Apanpa, o ni awọn ọdọkunrin naa lo kọkọ yinbọn si awọn oṣiṣẹ oun ki wọn to da ibọn naa pada.

O ṣalaye pe “Lasiko ti awọn eeyan wa de orita papa iṣere Liberty ti iṣẹlẹ ti waye, awọn ọdọ naa kọlu awọn eeyan wa pẹlu ibọn ati igo ni kete ti wọ foju ganni wọn.”

Adari Amotekun naa pari ọrọ rẹ pe ẹmi awọn ọmọ ikọ Amotekun ti sọnu ri lasiko irufẹ isẹlẹ bẹẹ lo jẹ ki awọn eeyan awọn wà ni igbaradi pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ.