Amosun bẹ̀rẹ̀ ìpoloǹgò ìbò fún olùdíje ADC, sọ̀rọ̀ tako Abiodun

Ibikunle Amosun

Gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun, ti fẹsun kan gomina to wa nipo, Ọmọọba Dapo Abiodun pe o ti kuna lati tẹlẹ akọsilẹ eto idagbasoke ipinlẹ naa.

Amosun, tii se Sẹneto to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, nile igbimọ aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oselu APC sọrọ yii nigba to darapọ mọ eto ipolongo ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ni papa igbafẹ Arcade to wa ni aafin Ake, niluu Abeokuta.

Amosun, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ba BBC Yoruba se laipẹ yii ni oun ti pagọ pẹlu oludije sipo gomina tẹgbẹ oṣelu ADC, Biyi Otegbeye lati tako oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu APC to wa, Gomina Dapo Abiodun.

Amosun lo fi ẹsun kan Dapo Abiodun pe o fi eru wọle sipo gomina nipinlẹ Ogun.

Mo n se atilẹyin fun Tinubu, ki ipo aarẹ le bọ si ẹkun guusu Naijiria – Amosun

Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oselu ADC sọrọ, Amosun ni, “Mo gbagbo pe ki Aare wa lati Guusu, idi niyi ti mo fi n se atileyin fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Gbogbo awọn alatilẹyin mi ninu oṣelu lo n ṣe atilẹyin fun Bola Ahmed Tinubu.

Amosun ni “Ohun meji lo wa ti mo n se lonii, akọkọ ni pe, latigba ti won ti da ipinle Ogun silẹ, ko si enikeni lati iwo oorun Ogun to je gomina. Awọn kan n sọ pe wọn ko si eniyan to kajue ṣugbọn mo mọ pe awọn to kaju rẹ wa, eyi ni ọkan ninu wọn, Biyi Otegbeye.

“Ekeji, a ti ṣeto ọna fun idagbasoke ni ipinlẹ Ogun, a ko si gbọdọ je ki o yẹ.

Amosun ni “Mo ti sọ tẹlẹ, ẹgbẹ APC ni mo wa ṣugbọn eto ti ijọba re ti fa silẹ nipinlẹ Ogun fun idagbasoke ipinlẹ naa ni Gomina Abiodun ko tẹle.

Nigba to n sọrọ, oludije sipo gomina, Otegbeye tẹnumọ pe ti oun ba wọle gẹgẹbi Gomina ipinlẹ Ogun, iṣẹ oun ni lati tesiwaju pelu awon igbese nla ti gomina tẹleri Amosun se, o ni erongba oun yoo wa lori ọrọ aje ipinlẹ naa.