Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó ní Buhari ti kú, Jubril Sudan ló ń darí Nàíjíríà

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Ọrọ t’awọn akọroyin kan sọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan TVC, “Journalists’ Hangout” pe Aarẹ Muhammadu Buhari tabuku ọkan lara awọn amin idanimọ Naijiria (Coat of Arms) l’awọn kan ti bẹrẹ si ni gbe kiri bayii pe Buhari ti kú.

Atọkun eto naa, Ayodele Osugbakun sọ pe ọpọ awọn ologun ni inu wọn ko dun si bi Buhari ṣe tẹ amin idanimọ Naijiria mọlẹ lasiko iranti awọn ọm’ogun to ti sun loju ija.

Awọn akọroyin naa ni iru rẹ ko ṣẹlẹ ri.

Awọn ọrọ yii ni awọn eeyan bẹrẹ si ni gba bi ẹni n gba igba ọti pe adari ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu ti sọ tẹlẹ pé Buhari ti ku lati ọdun 2017 pe ẹlomiran to n jẹ Jubril lati Sudan lo rọpo rẹ nigba naa.

Buhari funra rẹ si ti fesi si ahesọ ọrọ yii pe wọn ni oun ti ku, ati pe ẹlomiran ti rọpo oun lọdun 2018.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ohun t’awọn eeyan n sọ lori ayelujara ree:

Uzor Chukwu ni tiẹ fi fidio eto “Journalists’ Hangout ” lede loju opo Twitter rẹ nibi to ti sọ pe “eleyii fihan pe lootọọ ni Buhari ti kú, ẹlòmíràn si ti rọpo rẹ ni Aso Rock.”

Uzor ni gẹgẹ bi ọgagun ti Buhari jẹ, ko ni le tẹ amin idanimọ Naijiria mọlẹ laelae to ba jẹ pe Buhari gan an lo si wa lori oye.

Ẹlomiran tun lo fidio eto Journalists’Hangout lori Facebook nibi to ti sọ pe Buhari gangan ti jade laye.

Ohun ti Ndubisi Nkumeh sọ

Oríṣun àwòrán, @NKUMEH

Ohun ti Uzor Chukwu gbe soju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @UzorChukwu20

Ohun ti Blessing Uche sọ

Oríṣun àwòrán, Blessing Uche

Abọ iwadii BBC ree lori ọrọ awọn akọroyin to di iroyin ofege nipa Buhari

Awọn akọṣèmọṣẹ BBC to mọ nipa iroyin agbelẹrọ ti wa fidi rẹ mulẹ pe iroyin ofege ni ọrọ t’awọn akọroyin yii sọ lori eto Journalists’Hangout.

Wọn tiẹ tun sọ lori eto naa pe awọn oludamọran aarẹ ni wọn ṣi Buhari lọna pẹlu bo ṣe tẹ “Coat of Arms” mọlẹ.

Ọkan lara wọn, Jide Otitoju ni amin idanimọ yii ṣe pataki, o si jẹ ìyí ati ogo fun orilẹede ki orilẹ ede.

O ni amin idanimọ yii gan an tun ṣe pataki ju asia lọ.

Awọn akọroyin yii fẹnu ko lori eto naa pe o yẹ ki ẹni k’ẹni to ba ṣi aarẹ lọna gba ibawi tabi ijiya to yẹ.

Ohun ti ileeṣẹ aarẹ sọ ree:

Aarẹ Buhari ni ọjọ iranti awọn ologun to ti sun

Oríṣun àwòrán, The Presidency

Ninu esi rẹ, oludamọran fun aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ori ayelujara, Tolu Ogunlesi ni ko si ohun to jọọ pe Buhari tẹ amin idanimọ Naijiria mọlẹ.

Ogunlesi ṣalaye pe ohun ti Yoruba le pe ni edidi ni aarẹ tẹ mọlẹ lọjọ iranti awọn ọm’ogun to sun loju ija, kii ṣe amin idanimọ Naijiria.

Ayẹwo àwọn aworan ti Ogunlesi fi salaye ọrọ rẹ fihan pe Buhari ko duro lori amin idanimọ Naijiria.

Esi ti Tolu Ogunlesi sọ lorukọ ileesẹ aarẹ

Oríṣun àwòrán, Tolu Ogunlesi

Awọn akọroyin ori eto Journalists’Hangout ṣe atunṣe:

Ọgbẹni Otitoju pada salaye ninu fidio kan to fi sori YouTube lọjọ kejilelogun oṣu kinni pe aarẹ Buhari lẹtọọ lati duro lori edidi ọfiisi rẹ.

Bakan naa, akojọpọ fọto ati fidio ti BBC ṣe ayẹwo rẹ fihan pe Buhari ko tabuku Naijiria tabi ṣẹ si ofin nipa bi o ṣe duro lori edidi ọfiisi rẹ (seal of office).

Iwadii fihan pe ohun ti awọn aarẹ Naijiria maa n ṣe ni, koda ko yatọ lorilede Amerika naa.

Ti idaniloju si wa pe aarẹ Buhari gangan lo wa lori oye, kii se Jubril ti Sudan.