Agbẹjọ́rò Sunday Igboho fèsì padà fún Malami lórí ẹ̀sùn tuntun tó fẹ́ fi kan oníbàárà rẹ̀

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram

Amofin Yomi Aliyu, tii se asaaju ikọ agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho ti fun ijọba apapọ lesi lori bo se kede pe oun yoo fi ẹsun tuntun kan.

Bẹẹ ba gbagbe, ileẹjọ giga kan nilu Ibadan lo ti gbe idajọ kalẹ pe ki ajọ DSS ati ijọba apapọ san ogun biliọnu naira fun bi wọn se kọlu ile Sunday Igboho, ti wsn si tun ba dukia jẹ nibẹ.

Amọ agbẹjọro agba ati Minisita feto idajọ, Abubakar Malami lo kede ni Ọjọbọ pe ijọba yoo tun wọ Sunday Igboho ls sile ẹjọ fun ẹsun tuntun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n fesi si ọrọ yii, Yomi Aliyu wa n kọminu loju opo Facebook rẹ lori idi ti ijọba tun se fẹ fi ẹsun tuntun kan Sunday Igboho.

“O daju pe Malami ti faramọ bayii pe oun yoo tẹle asẹ ileẹjọ giga ni Ibadan titi ti yoo fi pe ẹjọ miran.

Esi ti agbẹjọro Sunday Igboho sọ pada fun Malami

Oríṣun àwòrán, Yomi Aliyu SAN/Facebook

Eyi tumọ si pe agbofinro tabi ijọba ko ni yaju, halẹ tabi pa Sunday Igboho titi ti ijọpa apapọ yoo fi pinnu lori ohun ti yoo se ati igbesẹ to tun kan.

Amọ ohun to n ya wa lẹnu ni pe irufẹ ẹsun tuntun wo tun ni Malami n tọka si yii!

A wa n ki pe layọ ni yoo gunlẹ pada wa lati New York nibi to ti fesi naa si ọrọ naa.”

Amin iyasọtọ kan

Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án – Malami

Abubakar Malami ati Sunday Igboho

Bi ina ko ba tan lasọ, ẹj ko le tan lori eekanna.

Afaimọ ki ijọba apapọ ma tun fi ẹsun mii kan ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Lọsẹ to lọ ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki ijọba apapọ san ogun biliọnu owo gba ma binu fún Igboho lori ikọlu ti ajọ DSS ṣe sí ile rẹ, nibi ti eeyan meji ti ku ti ọpọ dukia si ṣofo.

Àmọ́, agbẹjọro agba, to tun jẹ minisita eto ìdájọ, Abubakar Malami ti sọ pé ijoba lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ìdájọ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Malami sọ pe ijọba apapọ tun fi ẹsun tuntun kan Igboho.

Adájọ Ladiran Akintola paṣẹ pe kí agbẹjọro agba Malami ati ajọ DSS san owo gba ma binu naa lẹyin ikọlu lọjọ kinni oṣu keje.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àmọ́, Malami ni kò sì ohun ti ijọba apapọ n ṣe ti o lodi sí ofin.

“Ijọba ni ẹtọ lati sọ fun ile ẹjọ miran lati yi idajọ ile ẹjọ giga ilu Ibadan danu.

O sí tun le wu ijoba ko tun wa awọn ẹsun mii sí Igboho lẹsẹ.

Nitori naa, a n ṣe ayẹwo ẹjọ náà lọwọ láti mọ iru igbesẹ ti a fẹ gbe bayii,” Malami lo sọ bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ti ẹ ko ba gbagbe, Yomi Aliyu tó jẹ agbẹjọro Igboho lo pe Malami ati ajọ DSS lẹjọ lati san ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira fún Igboho gẹgẹ bi owo gba ma binu lẹyin ikólu DSS sí ile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igboho sí wa ni atimọle lorilede Benin nibi ti wọn ti mu ùn lọnà Irinajo rẹ si orilẹ ede Germany.

Aliyu ni ile ati awọn ọkọ bọginni bọginni olowo iyebiye ni wọn bajẹ nile Igboho nibi ti wọn tun ti pa eeyan meji.