Agbébọn jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ l’Eko

Aworan alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, BenjaminHundeyinfacebook

Awọn agbebọn ti ji eeyan mẹta to rinrinajo ori omi gbe lọ nipinlẹ Eko.

A gbọ pe agbegbe Apapa lawọn eeyan naa ti n bọ ki wọn to ji wọn gbe lagbegbe afara Falomo.

Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye pe, lootọ ni wọn ti gbọ iṣẹlẹ nipa ọhun, amọ awọn ko tii mọ orukọ awọn eeyan to bọ sọwọ awọn agbebọn naa.

Hundeyin tọka sii pe, awọn oṣiṣẹ ọlọpaa lati ẹka to wa fun iṣẹlẹ ori omi ti bọ soju iṣẹ lẹyẹ ọ sọka.

O ni “A gbọ iroyin pe wọn ji awọn mẹta kan gbe lọ lori omi, wọn ti ri ọkọ oju omi naa ni agbegbe Ikorodu.”

Hjundeyin ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari eeyan mẹta ti wọn ji gbe ọhun, atawọn to ji wọn gbe lọ.

Alukoro ọlọpaa ọhun fikun ọrọ rẹ pe pẹlu gbogbo iroyin ti wọn ti ni lori iṣẹlẹ naa, yoo ṣe iranwọ fun awọn agbofinro lati sa ipa wọn lati ṣawari awọn to wa ni igbekun ajinigbe naa lai farapa.

O fi kun pe awọn to ṣiṣẹ naa yoo foju wina ofin.